26 Mo wọn ẹgbẹta lé aadọta (650) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ohun èlò fadaka tí a wọ̀n tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti wúrà,
27 ogún àwo wúrà tí wọ́n tó ẹgbẹrun (1000) ìwọ̀n diramu ati ohun èlò idẹ meji tí ó ń dán, tí ó sì níye lórí bíi wúrà.
28 Mo sọ fún wọn pé, “A yà yín ati gbogbo nǹkan wọnyi sí mímọ́ fún OLUWA. Fadaka ati wúrà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín.
29 Ẹ máa tọ́jú wọn kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ títí tí ẹ óo fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn baálé baálé Israẹli ní Jerusalẹmu ninu yàrá ilé OLUWA.”
30 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gba fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò náà, wọ́n kó wọn wá sinu ilé Ọlọrun wa ní Jerusalẹmu.
31 Ní ọjọ́ kejila oṣù kinni ni a kúrò ní odò Ahafa à ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun wà pẹlu wa, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ati àwọn dánàdánà.
32 Nígbà tí a dé Jerusalẹmu a wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.