3 Bẹ́ẹ̀ ni èmi ni mo kọ́ Efuraimu ní ìrìn,mo gbé wọn lé ọwọ́ mi,ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé èmi ni mo wo àwọn sàn.
4 Mo fà wọ́n mọ́ra pẹlu okùn àánú ati ìdè ìfẹ́,mo dàbí ẹni tí ó tú àjàgà kúrò ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn,mo sì bẹ̀rẹ̀, mo gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn.
5 “Wọn óo pada sí ilẹ̀ Ijipti, Asiria óo sì jọba lé wọn lórí, nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.
6 A óo fi idà run àwọn ìlú wọn, irin ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè wọn yóo ṣẹ́, a óo sì pa wọ́n run ninu ibi ààbò wọn.
7 Àwọn eniyan mi ti pinnu láti yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí náà n óo ti àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn, kò sì ní sí ẹni tí yóo bá wọn bọ́ ọ.
8 “Mo ha gbọdọ̀ yọwọ́ lọ́rọ̀ yín ẹ̀yin Efuraimu?Mo ha gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Israẹli?Mo ha gbọdọ̀ pa ọ́ run bí mo ti pa Adimai run;kí n ṣe sí ọ bí mo ti ṣe sí Seboimu?Ọkàn mi kò gbà á,àánú yín a máa ṣe mí.
9 N kò ní fa ibinu yọ mọ́,n kò ní pa Efuraimu run mọ́,nítorí pé Ọlọrun ni mí,n kì í ṣe eniyan,èmi ni Ẹni Mímọ́ tí ó wà láàrin yín,n kò sì ní pa yín run.