Nehemaya 10:27-33 BM

27 Maluki, Harimu, ati Baana.

28 Àwọn eniyan yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn akọrin, àwọn iranṣẹ tẹmpili ati àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun, àwọn iyawo wọn, àwọn ọmọ wọn ọkunrin, àwọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́njú mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,

29 wọ́n parapọ̀ pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn ọlọ́lá wọn; wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé àwọn ó máa pa òfin Ọlọrun mọ́, àwọn óo sì máa tẹ̀lé e, bí Mose iranṣẹ rẹ̀ ti fún wọn. Wọ́n óo máa ṣe gbogbo ohun tí OLUWA tíí ṣe Oluwa wọn paláṣẹ, wọn ó sì máa tẹ̀lé ìlànà ati òfin rẹ̀.

30 A kò ní fi àwọn ọmọ wa obinrin fún àwọn ọmọ àwọn àlejò tí ń gbé ilẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọ wa.

31 Bí wọn bá sì kó ọjà tabi oúnjẹ wá tà ní ọjọ́ ìsinmi, a kò ní rà á lọ́wọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tabi ní ọjọ́ mímọ́ kankan.A óo sì yọ̀ǹda gbogbo èso ọdún keje keje, ati gbogbo gbèsè tí eniyan bá jẹ wá.

32 A óo sì tún fẹnu kò sí ati máa dá ìdámẹ́ta ṣekeli wá fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa lọdọọdun.

33 A óo máa pèsè burẹdi ìfihàn ati ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo, ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ati ti oṣù tuntun fún àwọn àsè tí wọ́n ti là sílẹ̀, ati fún gbogbo ohun mímọ́, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli kúrò, ati fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa.