Nehemaya 13 BM

Yíyẹra Kúrò lára Àwọn Àjèjì

1 Ní ọjọ́ náà, wọ́n kà ninu ìwé Mose sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan, ibẹ̀ sì ni a ti rí i kà pé àwọn ará Amoni ati àwọn ọmọ Moabu kò gbọdọ̀ wọ àwùjọ àwọn eniyan Ọlọrun,

2 nítorí pé wọn kò gbé oúnjẹ ati omi lọ pàdé àwọn ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu lọ́wẹ̀ láti máa gbé àwọn ọmọ Israẹli ṣépè, ṣugbọn Ọlọrun wa yí èpè náà pada sí ìre fún Israẹli.

3 Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ òfin náà, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì jáde kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

Àtúnṣe Tí Nehemaya ṣe

4 Kí ó tó di àkókò náà, Eliaṣibu alufaa, tí wọ́n yàn láti máa ṣe àkóso àwọn yàrá ilé Ọlọrun wa, tí ó sì ní àjọṣe pẹlu Tobaya,

5 ó ṣètò yàrá ńlá kan fún Tobaya níbi tí wọ́n ń tọ́jú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ sí, ati turari, àwọn ohun èlò ìrúbọ, pẹlu ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn akọrin, ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, pẹlu àwọn ohun tí wọ́n dá jọ fún àwọn alufaa gẹ́gẹ́ bí òfin.

6 N kò sí ní Jerusalẹmu ní gbogbo àkókò tí nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀, nítorí pé ní ọdún kejilelọgbọn ìjọba Atasasesi, ọba Babiloni, ni mo ti pada tọ ọba lọ. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, mo gba ààyè lọ́wọ́ ọba,

7 mo sì wá sí Jerusalẹmu, ìgbà náà ni mo wá rí nǹkan burúkú tí Eliaṣibu ṣe nítorí Tobaya, tí ó yọ yàrá fún ninu àgbàlá ilé Ọlọrun.

8 Inú bí mi gan-an, mo bá fọ́n gbogbo ẹrù Tobaya jáde kúrò ninu yàrá náà.

9 Mo bá pàṣẹ pé kí wọ́n tún yàrá náà ṣe kí ó mọ́, ẹ̀yìn náà ni mo wá kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun pada ati ọrẹ ẹbọ ohun sísun ati turari.

10 Mo tún rí i wí pé wọn kò fún àwọn ọmọ Lefi ní ẹ̀tọ́ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn akọrin, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ náà fi sá lọ sí oko wọn.

11 Nítorí náà, mo bá àwọn olórí wí, mo ní “Kí ló dé tí ilé Ọlọrun fi di àpatì?” Mo kó wọn jọ, mo sì dá wọn pada sí ààyè wọn.

12 Gbogbo àwọn ọmọ Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró wá sí ilé ìṣúra.

13 Mo bá yan àwọn kan tí yóo máa mójútó ètò ìsúná owó ní àwọn ilé ìṣúra. Àwọn ni: Ṣelemaya, alufaa, Sadoku, akọ̀wé, ati Pedaaya, ọmọ Lefi. Ẹni tí ó jẹ́ igbákejì wọn ni Hanani ọmọ Sakuri, ọmọ Matanaya, nítorí pé wọ́n mọ̀ wọ́n sí olóòótọ́, iṣẹ́ wọn sì ni láti fún àwọn arakunrin wọn ní ẹ̀tọ́ wọn.

14 Ọlọrun mi, ranti mi, nítorí nǹkan wọnyi, kí o má sì pa gbogbo nǹkan rere tí mo ti ṣe sí tẹmpili rẹ rẹ́ ati àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

15 Ní àkókò náà mo rí àwọn ọmọ Juda tí wọn ń fún ọtí waini ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń kó ìtí ọkà jọ, tí wọn ń dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí wọn sì ń gbé waini, ati èso girepu, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ ati oríṣìíríṣìí ẹrù wúwo wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi, mo bá kìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó yẹ kí wọ́n máa ta oúnjẹ.

16 Àwọn ọkunrin kan láti Tire pàápàá tí wọn ń gbé ààrin ìlú náà mú ẹja wá ati oríṣìíríṣìí àwọn nǹkan títà, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn eniyan Juda ati ni Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi.

17 Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo ní, “Irú nǹkan burúkú wo ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi?

18 Irú nǹkan burúkú yìí kọ́ ni àwọn baba yín pàápàá ṣe tí Ọlọrun fi mú kí ibi bá àwa ati ìlú yìí? Sibẹ, ẹ tún ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi, ẹ̀ ń fa ìrúnú Ọlọrun sórí Israẹli.”

19 Nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣú ní àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu kí ó tó di ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ìlẹ̀kùn, ati pé wọn kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀ títí tí ọjọ́ ìsinmi yóo fi rékọjá. Mo yan díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ mi sí àwọn ẹnubodè náà, kí wọ́n má baà kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.

20 Gbogbo àwọn oníṣòwò ati àwọn tí wọn ń ta oríṣìíríṣìí nǹkan sùn sí ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu bíi ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji.

21 Ṣugbọn mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ odi? Bí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ n óo jẹ yín níyà.” Láti ìgbà náà ni wọn kò wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.

22 Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n wá láti ṣọ́ àwọn ẹnubodè, kí wọn lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.Ranti eléyìí fún rere mi, Ọlọrun mi, kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀.

23 Nígbà náà, mo rí àwọn Juu tí wọn fẹ́ iyawo lára àwọn ará Aṣidodu, àwọn ará Amoni ati ti Moabu,

24 ìdajì àwọn ọmọ wọn ni kò gbọ́ èdè Juda àfi èdè Aṣidodu. Èdè àwọn àjèjì nìkan ni wọ́n gbọ́.

25 Mo bínú sí wọn mo sì gbé wọn ṣépè, mo na àwọn mìíràn, mo sì fa irun wọn tu. Mo sì mú wọn búra ní orúkọ Ọlọrun wí pé: “Ẹ kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọ wọn, tabi kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín tabi kí ẹ̀yin pàápàá fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn.

26 Ṣebí Solomoni ọba pàápàá dẹ́ṣẹ̀ nítorí ó fẹ́ irú àwọn obinrin bẹ́ẹ̀. Kò sí ọba tí ó dàbí rẹ̀ láàrin àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, Ọlọrun sì fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọrun sì fi jọba lórí gbogbo Israẹli, sibẹsibẹ, àwọn obinrin àjèjì ni wọ́n mú un dẹ́ṣẹ̀.

27 Ṣé a óo wá tẹ̀lé ìṣìnà yín, kí á sì máa ṣe irú nǹkan burúkú yìí, kí á sì máa fẹ́ àwọn obinrin àjèjì tí ó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọrun wa?”

28 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olórí alufaa, fẹ́ ọmọ Sanbalati ará Horoni kan, nítorí náà mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi.

29 Ranti, Ọlọrun mi, nítorí pé wọ́n rú òfin àwọn alufaa, wọn kò sì mú ẹ̀jẹ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi ṣẹ.

30 Nítorí náà mo wẹ̀ wọ́n mọ́ ninu gbogbo nǹkan àjèjì, mo sì fi ìdí iṣẹ́ wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alufaa ati ọmọ Lefi. Olukuluku sì ní iṣẹ́ tí ó ń ṣe,

31 mo pèsè igi ìrúbọ, ní àkókò tí ó yẹ ati àwọn èso àkọ́so.Ranti mi sí rere, Ọlọrun mi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13