Nehemaya 12 BM

Orúkọ Àwọn Alufaa ati Àwọn Ọmọ Lefi

1 Orúkọ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá Serubabeli ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua dé nìwọ̀nyí: Seraaya, Jeremaya ati Ẹsira,

2 Amaraya, Maluki, ati Hatuṣi,

3 Ṣekanaya, Rehumu, ati Meremoti,

4 Ido, Ginetoi, ati Abija,

5 Mijamini, Maadaya, ati Biliga,

6 Ṣemaaya, Joiaribu ati Jedaaya,

7 Salu ati Amoku, Hilikaya, ati Jedaaya. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí alufaa ati olórí àwọn arakunrin wọn ní ìgbà ayé Jeṣua.

8 Àwọn ọmọ Lefi ni: Jeṣua, Binui ati Kadimieli; Ṣerebaya, Juda, ati Matanaya, tí òun pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀ wà nídìí ètò àwọn orin ọpẹ́.

9 Bakibukaya ati Uno arakunrin wọn a máa dúró kọjú sí wọn ní àkókò ìsìn.

Àwọn Ìran Joṣua Olórí Alufaa

10 Joṣua ni baba Joiakimu, Joiakimu ni baba Eliaṣibu, Eliaṣibu ni baba Joiada,

11 Joiada ni baba Jonatani, Jonatani sì ni baba Jadua.

Àwọn Baálé Baálé ní Ìdílé Àwọn Alufaa

12 Nígbà tí Joiakimu jẹ́ olórí alufaa, àwọn alufaa wọnyi ní olórí baálé ní ìdílé tí a dárúkọ wọnyi:Meraya ni baálé ní ìdílé Seraaya,Hananaya ni baálé ní ìdílé Jeremaya,

13 Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ẹsira,Jehohanani ni baálé ní ìdílé Amaraya,

14 Jonatani ni baálé ní ìdílé Maluki,Josẹfu ni baálé ní ìdílé Ṣebanaya,

15 Adina ni baálé ní ìdílé Harimu,Helikai ni baálé ní ìdílé Meraiotu,

16 Sakaraya ni baálé ní ìdílé Ido,Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ginetoni,

17 Sikiri ni baálé ní ìdílé Abija,Pilitai ni baálé ní ìdílé Miniamini ati Moadaya,

18 Ṣamua ni baálé ní ìdílé Biliga,

19 Jehonatani ni baálé ní ìdílé Ṣemaaya,Matenai ni baálé ní ìdílé Joiaribu,

20 Usi ni baálé ní ìdílé Jedaaya,Kalai ni baálé ní ìdílé Salai,

21 Eberi ni baálé ní ìdílé Amoku,Haṣabaya ni baálé ní ìdílé Hilikaya,Netaneli ni baálé ní ìdílé Jedaaya.

Àkọsílẹ̀ Ìdílé Àwọn Alufaa ati ti Àwọn Ọmọ Lefi

22 Nígbà ayé Eliaṣibu ati Joiada, Johanani ati Jadua, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ṣe àkọsílẹ̀ àwọn baálé baálé ní ìdílé baba wọn títí di àkókò ìjọba Dariusi ọba Pasia.

23 Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn baálé baálé ninu àwọn ọmọ Lefi títí di ìgbà ayé Johanani ọmọ Eliaṣibu wà ninu ìwé Kronika.

Ìlànà Iṣẹ́ inú Tẹmpili

24 Àwọn tí wọ́n jẹ́ aṣiwaju ninu àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Haṣabaya, Ṣerebaya, ati Joṣua ọmọ Kadimieli pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró kọjú sí ara wọn, àwọn ìhà mejeeji yin Ọlọrun lógo wọ́n sì dúpẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi, eniyan Ọlọrun fi lélẹ̀.

25 Matanaya, Bakibukaya ati Ọbadaya, ati Meṣulamu, Talimoni, ati Akubu ni wọ́n jẹ́ olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà bodè tí wọn ń ṣọ́ àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ẹnubodè.

26 Gbogbo nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati nígbà ayé Nehemaya, gomina, ati Ẹsira Alufaa ati akọ̀wé.

Nehemaya Ṣe Ìyàsímímọ́ Odi Ìlú náà

27 Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ odi ìlú náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Lefi jọ láti gbogbo ibi tí wọ́n wà, wọ́n kó wọn wá sí Jerusalẹmu, láti wá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ náà pẹlu orin ọpẹ́ ati kimbali ati hapu.

28 Àwọn ìdílé akọrin bá kó ara wọn jọ láti gbogbo agbègbè Jerusalẹmu ati láti àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká Netofati,

29 bákan náà ni láti Betigiligali ati láti ẹkùn Geba, ati Asimafeti, nítorí pé àwọn akọrin kọ́ ìletò fún ara wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.

30 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àwọn eniyan ati àwọn bodè ati odi ìlú náà.

31 Mo bá kó àwọn ìjòyè Juda lọ sórí odi náà, mo sì yan ọ̀wọ́ meji pataki tí wọ́n ṣe ìdúpẹ́ tí wọ́n sì tò kọjá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.Àwọn kan tò lọ ní apá ọ̀tún odi náà lọ sí Ẹnubodè Ààtàn,

32 lẹ́yìn náà, Hoṣaaya ati ìdajì àwọn ìjòyè Juda tẹ̀lé wọn,

33 Ati Asaraya, Ẹsira ati Meṣulamu,

34 Juda, Bẹnjamini ati Ṣemaaya, ati Jeremaya.

35 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ alufaa tẹ̀lé wọn pẹlu fèrè.Àwọn nìwọ̀nyí: Sakaraya, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mikaaya, ọmọ Sakuri, ọmọ Asafu,

36 ati àwọn arakunrin rẹ̀ wọnyi: Ṣemaaya, Asareli ati Milalai, Gilalai, Maai ati Netaneli, Juda, ati Hanani, pẹlu àwọn ohun èlò orin Dafidi eniyan Ọlọ́run. Ẹsira, akọ̀wé, ni ó ṣáájú, àwọn eniyan sì tẹ̀lé e.

37 Ní Ẹnubodè Orísun, wọ́n gòkè lọ tààrà sí ibi àtẹ̀gùn ìlú Dafidi, ní igun odi ìlú, ní òkè ààfin Dafidi, títí lọ dé Ẹnubodè Omi ní apá ìlà oòrùn ìlú.

38 Ọ̀wọ́ keji àwọn tí wọ́n wá ṣe ìdúpẹ́ gba apá òsì, èmi náà sì tẹ̀lé wọn, pẹlu ìdajì àwọn eniyan, a gba orí odi náà lọ, a kọjá Ilé-ìṣọ́ ìléru, lọ sí ibi Odi Gbígbòòrò.

39 A rékọjá Ẹnubodè Efuraimu, a gba Ẹnubodè Àtijọ́, ati Ẹnubodè Ẹja ati Ilé-ìṣọ́ Hananeli ati Ilé-ìṣọ́ Ọgọrun-un, lọ sí Ẹnubodè Aguntan, wọ́n sì dúró ní Ẹnubodè àwọn Olùṣọ́ Tẹmpili.

40 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ́ mejeeji àwọn tí wọ́n wá ṣe ìdúpẹ́ ṣe dúró ninu ilé Ọlọrun, ati èmi pẹlu ìdajì àwọn baálé baálé. Àwọn tí wọ́n tún wà pẹlu mi nìwọ̀nyí:

41 àwọn alufaa: Eliakimu, Maaseaya ati Miniamini Mikaya, Elioenai, Sakaraya ati Hananaya, ń fun fèrè. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya,

42 Ṣemaaya, Eleasari ati Usi, Jehohanani, Malikija, Elamu, ati Eseri. Àwọn akọrin kọrin, Jesirahaya sì ni olórí wọn.

43 Wọ́n ṣe ìrúbọ pataki ní ọjọ́ náà, wọ́n sì yọ̀, nítorí Ọlọrun jẹ́ kí wọ́n yọ ayọ̀ ńlá, àwọn obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wọn náà yọ̀ pẹlu. Àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn réré sì gbúròó igbe ayọ̀ ní Jerusalẹmu.

Pípèsè fún Ìjọ́sìn Ní Tẹmpili

44 Ní ọjọ́ náà, wọ́n yan àwọn kan láti mójútó àwọn ilé ìṣúra, ati ọrẹ tí àwọn eniyan dájọ, àwọn èso àkọ́so, ati ìdámẹ́wàá, àwọn tí wọ́n yàn ni wọ́n ń mójútó pípín ẹ̀tọ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé òfin. Inú àwọn ará ilẹ̀ Juda dùn pupọ sí àwọn alufaa ati sí àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn.

45 Wọ́n ṣe ìsìn Ọlọrun ati ìsìn ìyàsímímọ́ bí àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ṣe, gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi ati ti ọmọ rẹ̀, Solomoni.

46 Nítorí pé látijọ́, ní ìgbà ayé Dafidi ati Asafu, wọ́n ní olórí fún àwọn akọrin, wọ́n sì ní àwọn orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.

47 Nígbà ayé Serubabeli ati Nehemaya, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli a máa fún àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà ní ẹ̀tọ́ wọn ojoojumọ, wọn a máa ya ìpín àwọn ọmọ Lefi náà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Lefi náà a sì máa ya ìpín àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13