1 Ọpọlọpọ àwọn eniyan náà, atọkunrin atobinrin, bẹ̀rẹ̀ sí tako àwọn Juu, arakunrin wọn.
2 Àwọn kan ń sọ pé, “Àwa, ati àwọn ọmọ wa, lọkunrin ati lobinrin, a pọ̀, ẹ jẹ́ kí á lọ wá ọkà, kí á lè máa rí nǹkan jẹ, kí á má baà kú.”
3 Àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti fi ilẹ̀ oko wa yáwó, ati ọgbà àjàrà wa, ati ilé wa, kí á lè rówó ra ọkà nítorí ìyàn tí ó mú yìí.”
4 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti yá owó láti lè san owó ìṣákọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ oko ati ọgbà àjàrà wa.
5 Bẹ́ẹ̀ sì ni, bí àwọn arakunrin wa ti rí ni àwa náà rí, àwọn ọmọ wa kò yàtọ̀ sí tiwọn; sibẹsibẹ, à ń fi túlààsì mú àwọn ọmọ wa lọ sóko ẹrú, àwọn ọmọbinrin wa mìíràn sì ti di ẹrú pẹlu bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkan tí a lè ṣe láti dáwọ́ rẹ̀ dúró, nítorí pé ní ìkáwọ́ ẹlòmíràn ni oko wa ati ọgbà àjàrà wa wà.”
6 Inú bí mi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn ati ohun tí wọn ń sọ.
7 Mo rò ó lọ́kàn mi, mo sì dá àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè lẹ́bi. Mo sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń ni àwọn arakunrin yín lára.”Mo bá pe ìpàdé ńlá lé wọn lórí, mo sọ fún wọn pé,
8 “Ní tiwa, a ti gbìyànjú níwọ̀n bí agbára wa ti mọ, a ti ra àwọn arakunrin wa tí wọ́n tà lẹ́rú fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pada, ṣugbọn ẹ̀yin tún ń ta àwọn arakunrin yín, kí wọ́n baà lè tún tà wọ́n fún wa!” Wọ́n dákẹ́, wọn kò sì lè fọhùn.
9 Mo wá sọ pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ máa fi ìbẹ̀rù rìn ní ọ̀nà Ọlọrun, kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wa má baà máa kẹ́gàn wa?
10 Pàápàá tí ó jẹ́ pé èmi ati àwọn arakunrin mi ati àwọn iranṣẹ mi ni à ń yá wọn ní owó ati oúnjẹ. Ẹ má gba èlé lọ́wọ́ wọn mọ́, ẹ sì jẹ́ kí á pa gbèsè wọn rẹ́.
11 Ẹ dá ilẹ̀ oko wọn pada fún wọn lónìí, ati ọgbà àjàrà wọn, ati ọgbà igi olifi wọn, ati ilé wọn, ati ìdá kan ninu ọgọrun-un owó èlé tí ẹ gbà, ati ọkà, waini, ati òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn.”
12 Wọ́n sì dáhùn pé, “A óo dá gbogbo rẹ̀ pada, a kò sì ní gba nǹkankan lọ́wọ́ wọn mọ́. A óo ṣe bí o ti wí.”Mo bá pe àwọn alufaa, mo sì mú kí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn yóo ṣe.
13 Mo gbọn àpò ìgbànú mi, mo ní, “Báyìí ni Ọlọrun yóo gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ kúrò ninu ilé rẹ̀ ati kúrò lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Ọlọrun yóo gbọn olúwarẹ̀ dànù lọ́wọ́ òfo.”Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà sì ṣe “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA. Àwọn eniyan náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ.
14 Siwaju sí i, láti ìgbà tí a ti yàn mí sí ipò gomina ní ilẹ̀ Juda, láti ogun ọdún tí Atasasesi ti jọba sí ọdún kejilelọgbọn, èmi ati arakunrin mi kò jẹ oúnjẹ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bíi gomina.
15 Àwọn gomina yòókù tí wọ́n jẹ ṣiwaju mi a máa ni àwọn eniyan lára, wọn a máa gba oúnjẹ mìíràn ati ọtí waini lọ́wọ́ wọn, yàtọ̀ sí ogoji ìwọ̀n Ṣekeli fadaka tí wọn ń gbà. Àwọn iranṣẹ wọn pàápàá a máa ni àwọn eniyan lára. Ṣugbọn, nítèmi, n kò ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo bẹ̀rù Ọlọrun.
16 Gbogbo ara ni mo fi bá wọn ṣiṣẹ́ odi mímọ, sibẹ n kò gba ilẹ̀ kankan, gbogbo àwọn iranṣẹ mi náà sì péjú sibẹ láti ṣiṣẹ́.
17 Siwaju sí i, aadọjọ (150) àwọn Juu ati àwọn ìjòyè ni wọ́n ń jẹun lọ́dọ̀ mi, yàtọ̀ sí àwọn tíí máa wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.
18 Mààlúù kan ati aguntan mẹfa tí ó dára ni wọ́n ń bá mi pa lojumọ, wọn a tún máa bá mi pa ọpọlọpọ adìẹ. Ní ọjọ́ kẹwaa kẹwaa ni wọ́n máa ń tọ́jú ọpọlọpọ waini sinu awọ fún mi. Sibẹsibẹ, n kò bèèrè owó oúnjẹ tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ gomina, nítorí pé ara tí ń ni àwọn eniyan pupọ jù.
19 Áà! Ọlọrun mi, ranti mi sí rere nítorí gbogbo rere tí mo ti ṣe fún àwọn eniyan wọnyi.