1 Lẹ́yìn tí a ti mọ odi náà tán, tí mo ti ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, tí mo sì ti yan àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, ati àwọn akọrin ati àwọn ọmọ Lefi,
2 mo yan arakunrin mi, Hanani, ati Hananaya, gomina ilé ìṣọ́, láti máa ṣe àkóso Jerusalẹmu, nítorí pé Hananaya jẹ́ olóòótọ́ ó sì bẹ̀rù Ọlọrun ju ọpọlọpọ àwọn yòókù lọ.
3 Mo sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ ṣí ẹnu ibodè Jerusalẹmu títí tí oòrùn yóo fi máa ta ni lára, kí wọ́n sì máa ti ibodè náà, kí wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú sí i lẹ́yìn kí àwọn olùṣọ́ tó kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Kí wọ́n yan àwọn olùṣọ́ láàrin àwọn ọmọ Jerusalẹmu, kí olukuluku ní ibùdó tirẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ibi tí ó bá kọjú sí ilé wọn.
4 Ìlú náà fẹ̀, ó sì tóbi, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ kéré níye, kò sì tíì sí ilé níbẹ̀.
5 Nígbà náà ni Ọlọrun fi sí mi lọ́kàn láti ranṣẹ pe àwọn ọlọ́lá jọ, ati àwọn olórí, ati àwọn eniyan yòókù, láti wá ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé tí wọ́n kọ orúkọ àwọn ìdílé tí wọ́n kọ́kọ́ wá sí, mo sì rí ohun tí wọ́n kọ sinu wọn pé:
6 Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí.
7 Wọ́n jọ dé pẹlu Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Asaraya, Raamaya, Nahamani, Modekai, Biliṣani, Misipereti, Bigifai, Nehumi, ati Baana.Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli nìyí:
8 Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa, ó lé mejilelaadọsan-an (2,172).
9 Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọrinlelọọdunrun ó dín mẹjọ (372).
10 Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652).
11 Àwọn ọmọ Pahati Moabu, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Jeṣua ati Joabu, jẹ́ ẹgbẹrinla ó lé mejidinlogun (2,818).
12 Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254).
13 Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ojilelẹgbẹrin ó lé marun-un (845).
14 Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ojidinlẹgbẹrin (760).
15 Àwọn ọmọ Binui jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé mẹjọ (648).
16 Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbẹta lé mejidinlọgbọn (628).
17 Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbaa ó lé ọọdunrun ati mejilelogun (2,322).
18 Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ọtalelẹgbẹta ati meje (667).
19 Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹtadinlaadọrin (2,067).
20 Àwọn ọmọ Adini jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín marun-un (655).
21 Àwọn ọmọ Ateri tí wọn ń jẹ́ Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un.
22 Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ ọọdunrun ó lé mejidinlọgbọn (328).
23 Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹrinlelogun (324).
24 Àwọn ọmọ Harifi jẹ́ aadọfa ó lé meji (112).
25 Àwọn ọmọ Gibeoni jẹ́ marundinlọgọrun-un.
26 Àwọn ará Bẹtilẹhẹmu ati Netofa jẹ́ ọgọsan-an ó lé mẹjọ (188).
27 Àwọn ará Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128).
28 Àwọn ará Beti Asimafeti jẹ́ mejilelogoji.
29 Àwọn ará Kiriati Jearimu ati Kefira ati Beeroti jẹ́ ọtadinlẹgbẹrin ó lé mẹta (743).
30 Àwọn ará Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta lé mọkanlelogun (621).
31 Àwọn ará Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122).
32 Àwọn ará Bẹtẹli ati Ai jẹ́ mẹtalelọgọfa (123).
33 Àwọn ará Nebo keji jẹ́ mejilelaadọta.
34 Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254).
35 Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320).
36 Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345).
37 Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mọkanlelogun (721).
38 Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ ẹgbaaji ó dín aadọrin (3,930).
39 Àwọn alufaa nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jedaaya, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Jeṣua, jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973).
40 Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052).
41 Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247).
42 Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017).
43 Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jeṣua, tí wọn ń jẹ́ Kadimieli, ní ìdílé Hodefa, jẹ́ mẹrinlelaadọrin.
44 Àwọn akọrin nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ mejidinlaadọjọ (148).
45 Àwọn olùṣọ́ ẹnubodè nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Ṣalumu, àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni, àwọn ọmọ Akubu, àwọn ọmọ Hatita, ati àwọn ọmọ Ṣobai. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogoje (138).
46 Àwọn iranṣẹ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa, ati àwọn ọmọ Tabaoti,
47 àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Sia, ati àwọn ọmọ Padoni,
48 àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba, ati àwọn ọmọ Ṣalimai,
49 àwọn ọmọ Hanani, àwọn ọmọ Gideli, ati àwọn ọmọ Gahari,
50 àwọn ọmọ Reaaya, àwọn ọmọ Resini, ati àwọn ọmọ Nekoda,
51 àwọn ọmọ Gasamu, àwọn ọmọ Usa, ati àwọn ọmọ Pasea,
52 àwọn ọmọ Besai, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefuṣesimu,
53 àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Hakufa, ati àwọn ọmọ Harihuri,
54 àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Hariṣa,
55 àwọn ọmọ Barikosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema,
56 àwọn ọmọ Nesaya, ati àwọn ọmọ Hatifa.
57 Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Sofereti, ati àwọn ọmọ Perida,
58 àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli,
59 àwọn ọmọ Ṣefataya, àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu, ati àwọn ọmọ Amoni.
60 Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ ninu tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392).
61 Àwọn tí wọ́n wá láti Teli Mela, ati láti Teli Hariṣa, Kerubu, Adoni, ati Imeri, ṣugbọn tí wọn kò mọ ilé baba wọn tabi ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀, tí kò sì sí ẹ̀rí tí ó dájú, bóyá ọmọ Israẹli ni wọ́n tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí:
62 àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Wọ́n jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé meji (642).
63 Bákan náà ni àwọn ọmọ alufaa wọnyi: àwọn ọmọ Hobaaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí wọ́n fẹ́ iyawo lára àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi, ṣugbọn tí wọn tún ń jẹ́ orúkọ àwọn àna wọn.)
64 Nígbà tí wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí wọn kò rí i, wọ́n yọ wọ́n kúrò lára àwọn alufaa, wọ́n sì kà wọ́n sí aláìmọ́.
65 Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fẹnu kan oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu yóo fi dé.
66 Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa ó lé ojidinnirinwo (42,360),
67 yàtọ̀ sí àwọn iranṣẹkunrin wọn ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin lé ọọdunrun ati mẹtadinlogoji (7,337), wọ́n sì ní àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245) lọkunrin ati lobinrin. Àwọn ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736),
68 àwọn ìbaaka wọn jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245),
69 àwọn ràkúnmí wọn jẹ́ ojilenirinwo ó dín marun-un (435), àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sì jẹ́ ẹgbaata ó lé ọrindinlẹgbẹrin (6,720).
70 Àwọn olórí ní ìdílé kọ̀ọ̀kan kópa ninu iṣẹ́ náà. Gomina fi ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati aadọta àwo kòtò, ati ẹẹdẹgbẹta ó lé ọgbọ̀n (530) ẹ̀wù alufaa sí i.
71 Àwọn kan ninu àwọn baálé baálé fi ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati ẹgbọkanla (2,200) òṣùnwọ̀n mina fadaka.
72 Ohun tí àwọn eniyan yòókù fi sílẹ̀ ni ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n diramu wúrà ati ẹgbaa (2,000) ìwọ̀n mina fadaka ati aṣọ àwọn alufaa mẹtadinlaadọrin.
73 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ìlú Juda, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn aṣọ́bodè, ati àwọn akọrin, ati díẹ̀ lára àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kaluku ń gbé ìlú rẹ̀.Nígbà tí yóo fi di oṣù keje, àwọn ọmọ Israẹli ti wà ní àwọn ìlú wọn.