Nehemaya 6 BM

Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Nehemaya

1 Nígbà tí wọ́n sọ fún Sanbalati ati Tobaya ati Geṣemu ará Arabia ati àwọn ọ̀tá wa yòókù pé a ti tún odi náà mọ, ati pé kò sí àlàfo kankan mọ́ (lóòótọ́ n kò tíì ṣe ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè).

2 Sanbalati ati Geṣemu ranṣẹ sí mi, wọ́n ní “Wá, jẹ́ kí á pàdé ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣugbọn wọ́n ti pète láti ṣe mí ní ibi.

3 Mo bá ranṣẹ pada sí wọn pé, mò ń ṣe iṣẹ́ pataki kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní yẹ kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àtiwá rí wọn.

4 Ìgbà mẹrin ni wọ́n ranṣẹ pè mí bẹ́ẹ̀, èsì kan náà sì ni mo fún wọn ní ìgbà mẹrẹẹrin.

5 Ní ìgbà karun-un, Sanbalati rán iranṣẹ rẹ̀ kan sí mi, ó kọ lẹta ṣugbọn kò fi òǹtẹ̀ lu lẹta náà.

6 Ohun tí ó kọ sinu lẹta náà ni pé:“A fi ẹ̀sùn kàn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, Geṣemu náà sì jẹ́rìí sí i pé, ìwọ ati àwọn Juu ń pète láti dìtẹ̀, nítorí náà ni ẹ fi ń mọ odi yín. Ìwọ ni o sì ń gbèrò láti jọba lé wọn lórí,

7 ati pé o tilẹ̀ ti yan àwọn wolii láti máa kéde nípa rẹ ní Jerusalẹmu pé, ‘Ọba kan wà ní Juda.’ Ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́ ìròyìn yìí. Nítorí náà, wá kí á jọ jíròrò nípa ọ̀rọ̀ náà.”

8 Mo ranṣẹ pada sí i pé, “Ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rárá, o kàn sọ ohun tí o rò lọ́kàn ara rẹ ni.”

9 Nítorí pé gbogbo wọn fẹ́ dẹ́rù bà wá, wọ́n lérò pé a óo jáwọ́ kúrò ninu iṣẹ́ náà, a kò sì ní lè parí rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn adura mi nisinsinyii ni, “Kí Ọlọrun, túbọ̀ fún mi ní okun.”

10 Ní ọjọ́ kan tí mo lọ sí ilé Ṣemaaya, ọmọ Delaaya, ọmọ Mehetabeli, tí wọ́n tì mọ́lé, ó ní “Jẹ́ kí á jọ pàdé ní ilé Ọlọrun ninu tẹmpili, nítorí wọ́n ń bọ̀ wá pa ọ́, alẹ́ ni wọ́n ó sì wá.”

11 Ṣugbọn mo dá a lóhùn pé, “Ṣé irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ? Àbí irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ sinu tẹmpili kí ó lọ máa gbé ibẹ̀? N kò ní lọ.”

12 Ó hàn sí mi pé kì í ṣe Ọlọrun ló rán an níṣẹ́ sí mi, ó kàn ríran èké sí mi ni, nítorí ti Tobaya ati Sanbalati tí wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀.

13 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀ kí ó lè dẹ́rù bà mí, kí n lè ṣe bí ó ti wí, kí n dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè bà mí ní orúkọ jẹ́, kí wọ́n wá kẹ́gàn mi.

14 Áà, Ọlọrun mi, ranti ohun tí Tobaya ati Sanbalati ati Noadaya, wolii obinrin, ṣe sí mi, ati àwọn wolii yòókù tí wọ́n fẹ́ máa dẹ́rù bà mí.

Ìparí Iṣẹ́ náà

15 A mọ odi náà parí ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù Eluli. Ó gbà wá ní ọjọ́ mejilelaadọta.

16 Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe.

17 Ati pé àwọn ọlọ́lá Juda ń kọ lẹta ranṣẹ sí Tobaya ní gbogbo àkókò yìí, Tobaya náà sì ń désì pada sí wọn.

18 Nítorí pé ọpọlọpọ àwọn ará Juda ni wọ́n ti bá a dá majẹmu, nítorí àna Ṣekanaya ọmọ Ara ni: ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Jehohanani, ló fẹ́ ọmọbinrin Meṣulamu, ọmọ Berekaya.

19 Wọn a máa sọ gbogbo nǹkan dáradára tí ó ń ṣe lójú mi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn a máa sọ ọ̀rọ̀ témi náà bá sọ fún un. Tobaya kò sì dẹ́kun ati máa kọ lẹta sí mi láti dẹ́rù bà mí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13