Nehemaya 8 BM

Ẹsira Ka Òfin fún Àwọn Eniyan náà

1 Ní ọjọ́ kinni oṣù náà, gbogbo wọn pátá péjọ pọ̀ sí gbangba ìta níwájú Ẹnubodè Omi, wọ́n sì sọ fún Ẹsira, akọ̀wé, pé kí ó mú ìwé òfin Mose tí OLUWA fún àwọn ọmọ Israẹli wá.

2 Ẹsira, alufaa, gbé ìwé òfin náà jáde siwaju àpéjọ náà, tọkunrin tobinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n lè gbọ́ kíkà òfin náà kí ó sì yé wọn ni wọ́n péjọ, ní ọjọ́ kinni oṣù keje.

3 Ẹsira ka ìwé òfin náà sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ó kọjú sí ìta gbangba tí ó wà lẹ́bàá Ẹnubode Omi láti àárọ̀ kutukutu títí di ọ̀sán, níwájú tọkunrin tobinrin ati àwọn tí ọ̀rọ̀ òfin náà yé, gbogbo wọn ni wọ́n sì tẹ́tí sí ìwé òfin náà.

4 Ẹsira, akọ̀wé, dúró lórí pèpéle tí wọ́n fi igi kàn fún un, fún ìlò ọjọ́ náà. Matitaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣema, Anaaya, Uraya, Hilikaya ati Maaseaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀, Pedaaya, Miṣaeli, Malikija, ati Haṣumu, Haṣibadana, Sakaraya ati Meṣulamu sì dúró ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀.

5 Ẹsira ṣí ìwé náà lójú gbogbo eniyan, nítorí pé ó ga ju gbogbo wọn lọ, bí ó ti ṣí ìwé náà gbogbo wọn dìde.

6 Ẹsira yin OLUWA, Ọlọrun, tí ó tóbi, gbogbo àwọn eniyan náà gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n dáhùn pé “Amin, Amin,” wọ́n tẹríba, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.

7 Àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Bani, Ṣerebaya, Jamini, Akubu, Ṣabetai, Hodaya, Maaseaya, Kelita, Asaraya, Josabadi, Hanani, ati Pelaaya ni wọ́n ń túmọ̀ àwọn òfin náà tí wọ́n sì ń ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan wọn, gbogbo àwọn eniyan dúró ní ààyè wọn.

8 Wọ́n ka òfin Ọlọrun ninu ìwé náà ketekete, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan, ó sì yé wọn.

9 Nehemaya tí ó jẹ́ gomina, ati Ẹsira, alufaa ati akọ̀wé, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n kọ́ àwọn eniyan náà sọ fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ má banújẹ́ tabi kí ẹ sọkún.” Nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n ń sọkún nígbà tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ inú òfin náà.

10 Nehemaya bá sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ, ẹ jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ mu waini dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ranṣẹ sí àwọn tí wọn kò bá ní, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA wa, ẹ má sì banújẹ́, nítorí pé ayọ̀ OLUWA ni agbára yín.”

11 Àwọn ọmọ Lefi rẹ àwọn eniyan náà lẹ́kún, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní, ẹ má bọkàn jẹ́.”

12 Gbogbo àwọn eniyan náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì fi oúnjẹ ati ohun mímu ranṣẹ sí àwọn eniyan wọn, wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá nítorí pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn.

Ayẹyẹ Ìpàgọ́

13 Ní ọjọ́ keji, àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan àwọn eniyan náà, pẹlu àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, péjọ sọ́dọ̀ Ẹsira, akọ̀wé, kí ó lè la ọ̀rọ̀ òfin náà yé wọn.

14 Wọ́n rí i kà ninu òfin tí OLUWA fún Mose pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé inú àgọ́ ní àkókò àjọ̀dún oṣù keje,

15 ati pé kí wọ́n kéde rẹ̀ ní gbogbo àwọn ìlú wọn ati ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ lọ sí orí àwọn òkè, kí ẹ sì mú àwọn ẹ̀ka igi olifi wá, ati ti paini, ati ti mitili, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka àwọn igi mìíràn láti fi pàgọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀.”

16 Àwọn eniyan náà jáde, wọ́n sì lọ wá imọ̀ ọ̀pẹ ati ẹ̀ka igi wá, wọ́n sì pàgọ́ fún ara wọn, kaluku pàgọ́ sí orí ilé, ati sí àgbàlá ilé wọn ati sí àgbàlá ilé Ọlọrun pẹlu, wọ́n pàgọ́ sí ìta Ẹnubodè Omi ati sí ìta Ẹnubodè Efuraimu.

17 Gbogbo àpéjọ àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú pa àgọ́, wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn. Láti ìgbà ayé Joṣua ọmọ Nuni, títí di àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kò pàgọ́ bẹ́ẹ̀ rí, gbogbo wọn sì yọ ayọ̀ ńlá.

18 Lojoojumọ, láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ tí àsè náà parí, ni wọ́n ń kà ninu ìwé òfin. Wọ́n ṣe àjọ̀dún àsè náà fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n pe àpéjọ tí ó lọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí ó wà ninu àkọsílẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13