Nehemaya 10:34-39 BM

34 A ti dìbò láàrin àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan, bí wọn yóo ṣe máa ru igi wá sí ilé Ọlọrun wa, ní oníléjilé, ní ìdílé ìdílé, ní àwọn àkókò tí a yàn lọdọọdun, tí wọn yóo fi máa rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin.

35 A ti gbà á bí ojúṣe wa pé àkọ́so èso ilẹ̀ wa ati àkọ́so gbogbo èso igi wa lọdọọdun, ni a óo máa gbé wá sí ilé OLUWA.

36 A óo máa mú àwọn àkọ́bí ọmọ wa, ati ti àwọn mààlúù wa lọ sí ilé Ọlọrun wa, fún àwọn alufaa tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àkọ́já ewébẹ̀ wa, ati àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn wa.

37 Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ kù, ati ọrẹ wa, èso gbogbo igi, ọtí waini, ati òróró. A óo máa kó wọn tọ àwọn alufaa lọ sí gbọ̀ngàn ilé Ọlọrun wa. A óo sì máa mú ìdámẹ́wàá èso ilẹ̀ wa lọ fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n máa ń gba ìdámẹ́wàá káàkiri gbogbo ilẹ̀ wa.

38 Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni yóo wà pẹlu àwọn ọmọ Lefi nígbà tí àwọn ọmọ Lefi bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóo yọ ìdámẹ́wàá gbogbo ìdámẹ́wàá tí wọ́n bá gbà lọ sí ilé Ọlọrun wa. Wọn óo kó o sinu gbọ̀ngàn ninu ilé ìpa-nǹkan-mọ́-sí.

39 Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Lefi yóo dá oúnjẹ, waini ati òróró jọ sinu àwọn gbọ̀ngàn, níbi tí àwọn ohun èlò tí a ti yà sí mímọ́ fún lílò ní ilé Ọlọrun wa, pẹlu àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ati àwọn olùṣọ́ tẹmpili, ati àwọn akọrin. A kò ní fi ọ̀rọ̀ ilé Ọlọrun wa falẹ̀.