13 ati àwọn arakunrin rẹ̀, àwọn baálé baálé lápapọ̀ jẹ́ ojilerugba ó lé meji (242).Amaṣisai, ọmọ Asareli, ọmọ Asai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Imeri,
14 ati àwọn arakunrin rẹ̀. Alágbára ati akọni eniyan ni wọ́n, wọ́n jẹ́ mejidinlaadoje (128). Sabidieli ọmọ Hagedolimu ni alabojuto wọn.
15 Àwọn ọmọ Lefi ni: Ṣemaaya, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Bunni.
16 Ṣabetai ati Josabadi, láàrin àwọn olórí ọmọ Lefi, ni wọ́n ń bojútó àwọn iṣẹ́ òde ilé Ọlọrun.
17 Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sabidi, ọmọ Asafu, ni olórí tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdúpẹ́ ninu adura, ati Bakibukaya tí ó jẹ́ igbákejì ninu àwọn arakunrin rẹ̀, Abuda, ọmọ Ṣamua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.
18 Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní ìlú mímọ́ náà jẹ́ ọrinlerugba ó lé mẹrin (284).
19 Àwọn aṣọ́nà ni, Akubu, Talimoni ati àwọn arakunrin wọn, àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ mejilelaadọsan-an (172).