Nehemaya 2:3-9 BM

3 Ẹ̀rù bà mí pupọ.Mo bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ẹ̀mí ọba gùn! Báwo ni ojú mi kò ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, ti di ahoro, tí iná sì ti jó àwọn ẹnubodè rẹ̀?”

4 Ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Kí ni ohun tí o wá fẹ́?”Nítorí náà, mo gbadura sí Ọlọrun ọ̀run.

5 Mo bá sọ fún ọba pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn, tí èmi iranṣẹ rẹ bá sì rí ojurere rẹ, rán mi lọ sí Juda, ní ìlú tí ibojì àwọn baba mi wà, kí n lọ tún ìlú náà kọ́.”

6 Ayaba wà ní ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba, ọba bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “O óo lò tó ọjọ́ mélòó lọ́hùn-ún? Ìgbà wo ni o sì fẹ́ pada?” Inú ọba dùn láti rán mi lọ, èmi náà sì dá ìgbà fún un.

7 Mo fún ọba lésì pé, “Bí ó bá tẹ́ kabiyesi lọ́rùn bẹ́ẹ̀, kí kabiyesi kọ̀wé lé mi lọ́wọ́ kí n lọ fún àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò, kí wọ́n lè jẹ́ kí n rékọjá lọ sí Juda,

8 kí ó kọ ìwé sí Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, kí ó fún mi ní igi kí n fi ṣe odi ẹnu ọ̀nà tẹmpili, ati ti odi ìlú, ati èyí tí n óo fi kọ́ ilé tí n óo máa gbé.” Ọba ṣe gbogbo ohun tí mo bèèrè fún mi, nítorí pé Ọlọrun lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ mi.

9 Mo bá tọ àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò lọ mo fún wọn ní lẹta tí ọba kọ. Ọba rán àwọn olórí ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tẹ̀lé mi.