1 Lẹ́yìn tí a ti mọ odi náà tán, tí mo ti ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, tí mo sì ti yan àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, ati àwọn akọrin ati àwọn ọmọ Lefi,
2 mo yan arakunrin mi, Hanani, ati Hananaya, gomina ilé ìṣọ́, láti máa ṣe àkóso Jerusalẹmu, nítorí pé Hananaya jẹ́ olóòótọ́ ó sì bẹ̀rù Ọlọrun ju ọpọlọpọ àwọn yòókù lọ.
3 Mo sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ ṣí ẹnu ibodè Jerusalẹmu títí tí oòrùn yóo fi máa ta ni lára, kí wọ́n sì máa ti ibodè náà, kí wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú sí i lẹ́yìn kí àwọn olùṣọ́ tó kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Kí wọ́n yan àwọn olùṣọ́ láàrin àwọn ọmọ Jerusalẹmu, kí olukuluku ní ibùdó tirẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ibi tí ó bá kọjú sí ilé wọn.
4 Ìlú náà fẹ̀, ó sì tóbi, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ kéré níye, kò sì tíì sí ilé níbẹ̀.