1 Lẹ́yìn tí a ti mọ odi náà tán, tí mo ti ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, tí mo sì ti yan àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, ati àwọn akọrin ati àwọn ọmọ Lefi,
2 mo yan arakunrin mi, Hanani, ati Hananaya, gomina ilé ìṣọ́, láti máa ṣe àkóso Jerusalẹmu, nítorí pé Hananaya jẹ́ olóòótọ́ ó sì bẹ̀rù Ọlọrun ju ọpọlọpọ àwọn yòókù lọ.
3 Mo sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ ṣí ẹnu ibodè Jerusalẹmu títí tí oòrùn yóo fi máa ta ni lára, kí wọ́n sì máa ti ibodè náà, kí wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú sí i lẹ́yìn kí àwọn olùṣọ́ tó kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Kí wọ́n yan àwọn olùṣọ́ láàrin àwọn ọmọ Jerusalẹmu, kí olukuluku ní ibùdó tirẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ibi tí ó bá kọjú sí ilé wọn.
4 Ìlú náà fẹ̀, ó sì tóbi, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ kéré níye, kò sì tíì sí ilé níbẹ̀.
5 Nígbà náà ni Ọlọrun fi sí mi lọ́kàn láti ranṣẹ pe àwọn ọlọ́lá jọ, ati àwọn olórí, ati àwọn eniyan yòókù, láti wá ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé tí wọ́n kọ orúkọ àwọn ìdílé tí wọ́n kọ́kọ́ wá sí, mo sì rí ohun tí wọ́n kọ sinu wọn pé:
6 Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí.
7 Wọ́n jọ dé pẹlu Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Asaraya, Raamaya, Nahamani, Modekai, Biliṣani, Misipereti, Bigifai, Nehumi, ati Baana.Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli nìyí: