Nehemaya 8:1-7 BM

1 Ní ọjọ́ kinni oṣù náà, gbogbo wọn pátá péjọ pọ̀ sí gbangba ìta níwájú Ẹnubodè Omi, wọ́n sì sọ fún Ẹsira, akọ̀wé, pé kí ó mú ìwé òfin Mose tí OLUWA fún àwọn ọmọ Israẹli wá.

2 Ẹsira, alufaa, gbé ìwé òfin náà jáde siwaju àpéjọ náà, tọkunrin tobinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n lè gbọ́ kíkà òfin náà kí ó sì yé wọn ni wọ́n péjọ, ní ọjọ́ kinni oṣù keje.

3 Ẹsira ka ìwé òfin náà sí etígbọ̀ọ́ wọn. Ó kọjú sí ìta gbangba tí ó wà lẹ́bàá Ẹnubode Omi láti àárọ̀ kutukutu títí di ọ̀sán, níwájú tọkunrin tobinrin ati àwọn tí ọ̀rọ̀ òfin náà yé, gbogbo wọn ni wọ́n sì tẹ́tí sí ìwé òfin náà.

4 Ẹsira, akọ̀wé, dúró lórí pèpéle tí wọ́n fi igi kàn fún un, fún ìlò ọjọ́ náà. Matitaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣema, Anaaya, Uraya, Hilikaya ati Maaseaya dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀, Pedaaya, Miṣaeli, Malikija, ati Haṣumu, Haṣibadana, Sakaraya ati Meṣulamu sì dúró ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀.

5 Ẹsira ṣí ìwé náà lójú gbogbo eniyan, nítorí pé ó ga ju gbogbo wọn lọ, bí ó ti ṣí ìwé náà gbogbo wọn dìde.

6 Ẹsira yin OLUWA, Ọlọrun, tí ó tóbi, gbogbo àwọn eniyan náà gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n dáhùn pé “Amin, Amin,” wọ́n tẹríba, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.

7 Àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Bani, Ṣerebaya, Jamini, Akubu, Ṣabetai, Hodaya, Maaseaya, Kelita, Asaraya, Josabadi, Hanani, ati Pelaaya ni wọ́n ń túmọ̀ àwọn òfin náà tí wọ́n sì ń ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn eniyan wọn, gbogbo àwọn eniyan dúró ní ààyè wọn.