1 Mo wọ inú ọgbà mi,arabinrin mi, iyawo mi.Mo kó òjíá ati àwọn turari olóòórùn dídùn mi jọ,mo jẹ afárá oyin mi, pẹlu oyin inú rẹ̀,mo mu waini mi ati wàrà mi.Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹ, kí ẹ sì mu,ẹ mu àmutẹ́rùn, ẹ̀yin olùfẹ́.
2 Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn.Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.Ṣílẹ̀kùn fún mi,arabinrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye,nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù,gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́.
3 Mo ti bọ́ra sílẹ̀,báwo ni mo ṣe lè tún múra?Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi,báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀?
4 Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn,ọkàn mi sì kún fún ayọ̀.
5 Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá,òróró òjíá sì ń kán ní ìka misára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn.
6 Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ.Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀,mo wá a, ṣugbọn n kò rí i,mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.