Orin Solomoni 8 BM

1 Ìbá wù mí kí o jẹ́ ọmọ ìyá mi ọkunrin,kí ó jẹ́ pé ọmú kan náà ni a jọ mú dàgbà.Bí mo bá pàdé rẹ níta,tí mo fẹnu kò ọ́ lẹ́nu,kì bá tí sí ẹni tí yóo fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.

2 Ǹ bá sìn ọ́ wá sílé ìyá mi,ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó tọ́ mi,ǹ bá fún ọ ní waini dídùn mu,àní omi èso Pomegiranate mi.

3 Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní ìgbèrí mi,kí o sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ fà mí mọ́ra!

4 Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin obinrin Jerusalẹmu,pé ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi,títí tí yóo fi wù ú láti jí.

Orin Kẹfa

5 Ta ní ń bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó fara ti olùfẹ́ rẹ̀?Lábẹ́ igi èso ápù ni mo ti jí ọ,níbi tí ìyá rẹ ti rọbí rẹ,níbi tí ẹni tí ó bí ọ ti rọbí.

6 Gbé mi lé oókan àyà rẹ bí èdìdì ìfẹ́,bí èdìdì, ní apá rẹ;nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú.Owú jíjẹ burú, àfi bí isà òkú.A máa jó bí iná,bí ọwọ́ iná tí ó lágbára.

7 Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́,ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì.Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́,ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà.

8 A ní àbúrò obinrin kékeré kan,tí kò lọ́mú.Kí ni kí á ṣe fún arabinrin wa náàní ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀?

9 Bí ó bá jẹ pé ògiri ni arabinrin wa,à óo mọ ilé-ìṣọ́ fadaka lé e lórí.Bí ó bá jẹ́ pé ìlẹ̀kùn ni,pákó Kedari ni a óo fi yí i ká.

10 Ògiri ni mí,ọmú mi sì dàbí ilé-ìṣọ́;ní ojú olùfẹ́ mi,mo ní alaafia ati ìtẹ́lọ́rùn.

11 Solomoni ní ọgbà àjàrà kan,ní Baali Hamoni.Ó fi ọgbà náà fún àwọn tí wọn yá a,ó ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n owó fadaka wá,fún èso ọgbà rẹ̀.

12 Èmi ni mo ni ọgbà àjàrà tèmi,ìwọ Solomoni lè ní ẹgbẹrun ìwọ̀n owó fadaka,kí àwọn tí wọn yá ọgbà sì ní igba.

13 Ìwọ tí ò ń gbé inú ọgbà,àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ń dẹtí,jẹ́ kí n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

14 Yára wá, olùfẹ́ mi,yára bí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín,sí orí àwọn òkè turari olóòórùn dídùn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8