Orin Solomoni 2 BM

1 Òdòdó Ṣaroni ni mí,ati òdòdó Lílì tí ó wà ninu àfonífojì.

2 Bí òdòdó lílì ti rí láàrin ẹ̀gún,ni olólùfẹ́ mi rí láàrin àwọn ọmọge.

3 Bí igi ápù ti rí láàrin àwọn igi igbó,ni olùfẹ́ mí rí láàrin àwọn ọmọkunrin.Pẹlu ìdùnnú ńlá ni mo fi jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀,èso rẹ̀ sì dùn lẹ́nu mi.

4 Ó mú mi wá sí ilé àsè ńlá,ìfẹ́ ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.

5 Fún mi ni èso àjàrà gbígbẹ jẹ,kí ara mi mókun,fún mi ní èso ápù jẹ kí ara tù mí,nítorí pé, àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.

6 Ó wù mí kí ọwọ́ òsì rẹ̀ wà ní ìgbèrí mi,kí ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fà mí mọ́ra.

7 Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,ní orúkọ egbin, ati ti àgbọ̀nrín pé,ẹ kò gbọdọ̀ jí ìfẹ́ títí yóo fi wù ú láti jí.

Orin Keji

8 Mo gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi, wò ó! Ó ń bọ̀,ó ń fò lórí àwọn òkè ńlá,ó sì ń bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.

9 Olólùfẹ́ mi dàbí egbin,tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín.Wò ó! Ó dúró lẹ́yìn ògiri ilé wa,ó ń yọjú lójú fèrèsé,ó ń yọjú níbi fèrèsé kékeré tí ó wà lókè.

10 Olùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó wí fún mi pé,“Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ.”

11 Àkókò òtútù ti lọ,òjò sì ti dáwọ́ dúró.

12 Àwọn òdòdó ti hù jáde,àkókò orin kíkọ ti tó,a sì ti ń gbọ́ ohùn àwọn àdàbà ní ilẹ̀ wa.

13 Àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń so èso,àjàrà tí ń tanná,ìtànná wọn sì ń tú òórùn dídùn jáde.Dìde, olùfẹ́ mi, arẹwà mi,jẹ́ kí á máa lọ.

14 Àdàbà mi, tí ó wà ninu pàlàpálá òkúta,ní ibi kọ́lọ́fín òkúta,jẹ́ kí n rójú rẹ, kí n gbọ́ ohùn rẹ,nítorí ohùn rẹ dùn, ojú rẹ sì dára.

15 Mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ wọ̀n-ọn-nì,àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí wọn ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,nítorí ọgbà àjàrà wa tí ń tanná.

16 Olùfẹ́ mi ni ó ni mí, èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi,ó ń da àwọn ẹran rẹ̀, wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì.

17 Tún pada wá! Olùfẹ́ mi,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,tí òjìji kò ní sí mọ́.Pada wá bí egbin ati akọ àgbọ̀nrín,lórí àwọn òkè págunpàgun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8