Orin Solomoni 7 BM

1 Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà,ìwọ, ọmọ aládé.Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́,tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe.

2 Ìdodo rẹ dàbí abọ́,tí kì í gbẹ fún àdàlú waini,ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà,tí a fi òdòdó lílì yíká.

3 Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji,tí wọn jẹ́ ìbejì.

4 Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́.Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni,tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu.Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni,tí ó dojú kọ ìlú Damasku.

5 Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli,irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn.

6 O dára, o wuni gan-an,olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin.

7 Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ,ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà.

8 Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún,kí n di odi rẹ̀ mú.Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà,kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù.

9 Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ,tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun,tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín.

10 Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́.

11 Máa bọ̀, olùfẹ́ mi,jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá,kí á lọ sùn ní ìletò kan.

12 Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu,kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé,bóyá ó ti ń tanná;kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná,níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.

13 Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde,ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni,tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi,ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8