Orin Solomoni 3 BM

1 Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,lórí ibùsùn mi lálẹ́,mo wá a, ṣugbọn n kò rí i;mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.

2 N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú,n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede.Mo wá a ṣugbọn n kò rí i.

3 Àwọn aṣọ́de rí mi,bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú.Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé,“Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4 Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn,ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ,títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi,ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi.

5 Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra,pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí.

Orin Kẹta

6 Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó dàbí òpó èéfín,tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari,pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò?

7 Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀,ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli,ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká.

8 Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà,akọni sì ni wọ́n lójú ogun.Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́.

9 Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀.

10 Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀,ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀,Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8