Orin Solomoni 1 BM

1 Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí:

Orin Kinni

2 Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu,nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ.

3 Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn,orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde;nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ.

4 Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá,ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀.Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹa óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ;abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!

5 Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà,mo dàbí àgọ́ Kedari,mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni.

6 Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú,oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀.Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi,wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà,ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.

7 Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́:níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko?Níbo ni wọ́n ti ń sinmi,nígbà tí oòrùn bá mú?Kí n má baà máa wá ọ kiri,láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?

8 Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin,bí o kò bá mọ ibẹ̀,ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran.Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹkolẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan.

9 Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao.

10 Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà.

11 A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà,tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ.

12 Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀,turari mi ń tú òórùn dídùn jáde.

13 Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá,bí ó ti sùn lé mi láyà.

14 Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi,ninu ọgbà àjàrà Engedi.

15 Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi;o lẹ́wà pupọ.Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà.

16 Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi,o lẹ́wà gan-an ni.Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa.

17 Igi Kedari ni òpó ilé wa,igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8