Orin Solomoni 4 BM

1 Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi,ẹwà rẹ pọ̀.Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ,irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́,tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi.

2 Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,tí wọn wá fọ̀;gbogbo wọn gún régé,Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn.

3 Ètè rẹ dàbí òwú pupa;ẹnu rẹ fanimọ́ra,ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate,lábẹ́ ìbòjú rẹ.

4 Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,tí a kọ́ fún ihamọra,ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ dàbí ẹgbẹrun (1000) asà tí a kó kọ́,bí apata àwọn akọni jagunjagun tí a kó jọ.

5 Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì,tí wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì.

6 N óo wà lórí òkè òjíá,ati lórí òkè turari,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,tí òkùnkùn yóo sì lọ.

7 O dára gan-an ni, olùfẹ́ mi!O dára dára, o ò kù síbìkan,kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ.

8 Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi,máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni.Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana,kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni,kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé.

9 O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi,ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí,pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ,ni o ti kó sí mi lórí.

10 Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi,ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ.Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ.

11 Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi,wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni.

12 Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀.Ọgbà tí a tì ni iyawo mi;àní orísun omi tí a tì ni ọ́.

13 Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate,tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ,àwọn bíi igi hena ati nadi;

14 igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni,pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari,igi òjíá, ati ti aloe,ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ.

15 Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́,kànga omi tútù,àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8