Aisaya 1 BM

1 Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Juda ati Jerusalẹmu nìyí, nígbà ayé Usaya, Jotamu, Ahasi, ati Hesekaya, àwọn ọba Juda.

OLUWA Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Wí

2 Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run,sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayéNítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ,tí mo tọ́ wọn dàgbà tán,ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi.

3 Mààlúù mọ olówó rẹ̀;kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un;ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan,òye kò yé àwọn eniyan mi.”

4 Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀,àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ,ìran oníṣẹ́ ibi;àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́!Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀,wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹliwọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i.

5 Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni,àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò,gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì.

6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín,kò síbìkan tí ó gbádùn.Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀.Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn.

7 Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro,wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀.

8 Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà,ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí;ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì.

9 Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni,à bá rí bí i Sodomu,à bá sì dàbí Gomora.

10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin ìjòyè Sodomu:Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa,ẹ̀yin ará Gomora

11 OLUWA ní,“Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi?Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́;bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa.N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.

12 Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.

13 Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́;ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi.Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ.Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.

14 Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín.Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi,n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi.

15 “Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura,n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín.Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbaduran kò ní gbọ́;nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀,

16 Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká.Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́.Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.

17 Ẹ lọ kọ́ bí eniyan tí ń ṣe rere.Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́.Ẹ máa ran ẹni tí ara ń ni lọ́wọ́.Ẹ máa gbìjà aláìníbaba, kí ẹ sì máa gba ẹjọ́ opó rò.”

18 OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀.Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná,yóo di funfun bí ẹfun.Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì,yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.

19 Bí ẹ bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́ràn,ẹ óo jẹ ire ilẹ̀ náà.

20 Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣoríkunkun;idà ni yóo run yín.”Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.

Ìlú tí Ó kún fún Ẹ̀ṣẹ̀

21 Ìlú tí ó ti jẹ́ olódodo rí tí ń ṣe bí aṣẹ́wó,ìlú tí ó ti kún fún ẹ̀tọ́ ati òdodo rí, ti kún fún ìpànìyàn.

22 Fadaka rẹ ti di ìdàrọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.Wọ́n ti fi omi lú ọtí waini rẹ.

23 Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn ìjòyè rẹ, ati ẹgbẹ́ olè;gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì ń wá ẹ̀bùn káàkiri.Wọn kì í gbèjà aláìníbaba,bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba ẹjọ́ opó rò.

24 Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Alágbára Israẹli ní:“N óo bínú sí àwọn ọ̀tá mi,n óo sì gbẹ̀san lára àwọn tí ó kórìíra mi.

25 Nígbà tí mo bá gbá ọ mú,n óo finá jó gbogbo àìdára rẹ dànù.N óo sì mú gbogbo ìbàjẹ́ rẹ kúrò.

26 N óo dá àwọn onídàájọ́ rẹ pada sí ipò tí wọn ti wà tẹ́lẹ̀.Ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ,lẹ́yìn náà a óo máa pè ọ́ ní ìlú olódodo.”

27 A óo fi ẹ̀tọ́ ra Sioni pada;a óo sì fi òdodo ra àwọn tí ó bá ronupiwada ninu rẹ pada.

28 Ṣugbọn a óo pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run,àwọn tí ó kọ OLUWA sílẹ̀ yóo sì ṣègbé.

29 Ojú yóo tì yín, fún àwọn igi Oaku tí ẹ nífẹ̀ẹ́ láti máa bọ.Ojú yóo sì tì yín fún àwọn ọgbà oriṣa tí ẹ yàn.

30 Nítorí pé ẹ óo dàbí igi oaku tí ó wọ́wé,ati bí ọgbà tí kò lómi.

31 Alágbára yóo dàbí ògùṣọ̀,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ìṣáná.Àwọn mejeeji ni yóo jóná pọ̀,kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa iná náà.