1 Wọ́n ti kó àgbò láti Sela, ní ọ̀nà aṣálẹ̀,wọ́n fi ranṣẹ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, ní òkè Sioni.
2 Àwọn ọmọbinrin Moabu dúró létí odò Anoni,wọ́n ń rìn síwá, sẹ́yìn,wọ́n ń lọ sókè, sódò,bí ọmọ ẹyẹ tí a lé kúrò ninu ìtẹ́.
3 “Gbà wá ní ìmọ̀ràn,máa ṣe ẹ̀tọ́ fún wa.Fi òjìji rẹ dáàbò bò wá,kí ara lè tù wá lọ́sàn-án gangan,bí ẹni pé alẹ́ ni.Dáàbò bo àwọn tí a lé jáde;má tú àṣírí ẹni tí ń sálọ.
4 Jẹ́ kí àwọn tí a lé jáde ní Moabu, máa gbé ààrin yín.Dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn apanirun.”Nígbà tí aninilára kò bá sí mọ́ tí ìparun bá dópin,tí atẹnimọ́lẹ̀ bá ti kúrò ní ilẹ̀ náà.
5 Nígbà náà a óo fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ pẹlu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.Ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo yóo jókòó lórí ìtẹ́ náà,Yóo dúró lórí òtítọ́ ní ìdílé Dafidi.
6 A ti gbọ́ ìròyìn ìgbéraga Moabu,bí ó ṣe ń ṣe àfojúdi tí ó sì ń sọ ìsọkúsọ:ṣugbọn lásán ni ìgbéraga rẹ̀.
7 Nítorí náà, kí Moabu máa pohùnréré ẹkún,kí gbogbo eniyan máa sun ẹkún arò ní Moabu.Wọn óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,nígbà tí wọn ba ranti àkàrà Kiri Heresi,tí ó ní èso àjàrà ninu.
8 Gbogbo oko ni ó rọ ní Heṣiboni;bẹ́ẹ̀ náà ni ọgbà Sibuma:àwọn olórí orílẹ̀-èdè ti gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lulẹ̀,èyí tí ó tàn kálẹ̀ dé Jaseri títí dé inú aṣálẹ̀.Ìtàkùn rẹ̀ tàn kálẹ̀,wọ́n kọjá sí òdìkejì òkun.
9 Nítorí náà mo sọkún fún ọgbà àjàrà Sibumabí mo ṣe sọkún fún Jaseri;mo sì sọkún nítorí Heṣiboni ati Eleale,mo sọkún, omi ń dà lójú mi pòròpòrònítorí gbogbo ìkórè yín, ati èso oko yín ni ogun ti kó lọ.
10 Wọ́n ti kó ayọ̀ ati ìdùnnú lọ kúrò ninu oko eléso;ẹnikẹ́ni kò kọrin bẹ́ẹ̀ ni kò sí ariwo híhó ninu ọgbà àjàrà wọn.Kò sí àwọn tí ó ń pọn ọtí ninu rẹ̀ mọ́bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ariwo àwọn tí ń pọn ọtí mọ́.
11 Nítorí náà, ẹ̀mí mi kọrin arò bíi ti dùùrù fún Moabu,ọkàn mi kérora, fún Moabu ati Kiri Heresi.
12 Nígbà tí Moabu bá wá siwaju,tí ó fi gbogbo agbára gbadura ninu ilé oriṣa rẹ̀,títí ó fi rẹ̀ ẹ́,adura rẹ̀ kò ní gbà.
13 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti kọ́ sọ nípa Moabu tẹ́lẹ̀ nìyí.
14 Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA ní, “Nígbà tí a óo fi rí ọdún mẹta, tíí ṣe iye ọdún alágbàṣe, a óo ti sọ ògo Moabu di ilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan inú rẹ̀ pọ̀, àwọn díẹ̀ ni yóo ṣẹ́kù, àárẹ̀ yóo sì ti mú wọn.”