Aisaya 3 BM

Ìdàrúdàpọ̀ Ní Jerusalẹmu

1 Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo múgbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò,ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda.Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé,ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀.

2 Yóo mú àwọn alágbára ati àwọn ọmọ ogun kúrò,pẹlu àwọn onídàájọ́ ati àwọn wolii,àwọn aláfọ̀ṣẹ ati àwọn àgbààgbà;

3 àwọn olórí aadọta ọmọ ogun, ati àwọn ọlọ́lá,àwọn adáhunṣe ati àwọn pidánpidán, ati àwọn olóògùn.

4 Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn,àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn.

5 Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn,olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀,àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn.Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà,àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá.

6 Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀,ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé,“Ìwọ ní aṣọ ìlékè,nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa;gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.”

7 Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé,“Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe.N kò ní oúnjẹ nílébẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ.Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.”

8 Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀,Juda sì ti ṣubú.Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA,wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀.

9 Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n;wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu:Wọn kò fi bò rárá.Ègbé ni fún wọn,nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn.

10 Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọnnítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn.

11 Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú,kò ní dára fún wọn.Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

12 Ẹ wá wo àwọn eniyan mi!Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi;àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí.Ẹ̀yin eniyan mi,àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà,wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú.

OLUWA Dá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Lẹ́jọ́

13 OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀;ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́

14 OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀siwaju ìtẹ́ ìdájọ́,yóo sọ fún wọn pé;“Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run,ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín.

15 Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́,tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?”

Ìkìlọ̀ fún Àwọn Obinrin Jerusalẹmu

16 OLUWA ní,“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dúnbí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.

17 OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;yóo ṣí aṣọ lórí wọn.”

18 Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn;

19 ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn.

20 Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn,

21 òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú,

22 ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò

23 ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá.

24 Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara,okùn yóo wà dípò ọ̀já;orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́,aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye.Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà.

25 Idà ni yóo pa àwọn ọkunrin yín,àwọn akikanju yín yóo kú sógun.

26 Ọ̀fọ̀ ati ẹkún yóo pọ̀ ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu.Yóo dàbí obinrin tí wọ́n tú sí ìhòòhò,tí ó jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀.