1 Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Babiloni:
2 Ẹ ta àsíá ní orí òkè gíga,ẹ gbóhùn sókè sí wọn.Ẹ juwọ́, kí àwọn ológun gba ẹnu ibodè àwọn ọlọ́lá wọlé.
3 Èmi pàápàá ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yà sọ́tọ̀,mo ti pe àwọn akọni mi, tí mo fi ń yangàn,láti fi ibinu mi hàn.
4 Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan,gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀!OLUWA àwọn ọmọ ogunní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun.
5 Wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè,láti ìpẹ̀kun ayé.OLUWA ń bọ̀ pẹlu àwọn ohun ìjà ibinu rẹ̀,tí yóo fi pa gbogbo ayé run.
6 Ẹ pohùnréré ẹkún,nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé,yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare.
7 Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ,ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì;
8 ẹnu yóo sì yà wọ́n.Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn,wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí;wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu,ojú yóo sì tì wọ́n.
9 Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán,tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro,ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
10 Nítorí àgbájọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀runyóo kọ̀, wọn kò ní tan ìmọ́lẹ̀.Oòrùn yóo ṣókùnkùn nígbà tí ó bá yọ,òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀.
11 N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀,n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga,n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀.
12 N óo sọ eniyan di ohun tí ó ṣọ̀wọ́n ju wúrà dáradára lọ,irú eniyan yóo ṣọ̀wọ́n ju wúrà ilẹ̀ Ofiri lọ.
13 Nítorí náà n óo mú kí àwọn ọ̀run wárìrìayé yóo sì mì tìtì tóbẹ́ẹ̀ tí yóo sún kúrò ní ipò rẹ̀,nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ bá ru.
14 Eniyan yóo dàbí àgbọ̀nrín tí ọdẹ ń lé,ati bí aguntan tí kò ní olùṣọ́;olukuluku yóo doríkọ ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀,wọn óo sì sá lọ sí ilẹ̀ wọn.
15 Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí, wọn óo fi ọ̀kọ̀ gún un pa,ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀, idà ni wọ́n ó fi pa á.
16 A óo so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ lójú wọn,a óo kó ilé wọn,a óo sì bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀ pẹlu agbára.
17 Wò ó! N óo rú àwọn ará Media sókè sí wọn,àwọn tí wọn kò bìkítà fún fadakabẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka wúrà sí.Wọn óo wá bá Babiloni jà.
18 Wọn yóo fi ọfà pa àwọn ọdọmọkunrin,wọn kò ní ṣàánú oyún inú,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣàánú àwọn ọmọde.
19 Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé,ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea,yóo dàbí Sodomu ati Gomora,nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run.
20 Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran,àwọn ará Arabia kankan kò ní pa àgọ́ sibẹ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn darandaran kankan kò ní jẹ́ kí agbo aguntan wọn sinmi níbẹ̀.
21 Ṣugbọn àwọn ẹranko ní yóo máa sùn níbẹ̀ilé rẹ̀ yóo sì kún fún ẹyẹ òwìwí,ògòǹgò yóo máa gbè ibẹ̀ẹhànnà òbúkọ yóo sì máa ta pọ́núnpọ́nún káàkiri ibẹ̀.
22 Àwọn ìkookò yóo máa ké ninu ilé ìṣọ́ rẹ̀,ààfin rẹ̀ yóo di ibùgbé àwọn ajáko,àkókò rẹ̀ súnmọ́ etílé,ọjọ́ rẹ̀ kò sì ní pẹ́ mọ́.