1 O óo sọ ní ọjọ́ náà pé,“N óo fi ọpẹ́ fún OLUWA,nítorí pé bí ó tilẹ̀ bínú sí mi,inú rẹ̀ ti rọ̀, ó sì tù mí ninu.
2 Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi,n óo gbẹ́kẹ̀lé eẹ̀rù kò sì ní bà mí,nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi,òun sì ni Olùgbàlà mi.”
3 Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlàbí ẹni pọn omi láti inú kànga.
4 Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé,“Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA,ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga.
5 Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWAnítorí ó ṣe nǹkan tí ó lógo,jẹ́ kí èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé.
6 Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni,ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni,nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹlití ó wà láàrin yín.”