Aisaya 35 BM

Ọ̀nà Ìwà Mímọ́

1 Inú aṣálẹ̀ ati ilẹ̀ gbígbẹ yóo dùn,aṣálẹ̀ yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo rúwé, yóo sì tanná.

2 Nítòótọ́ yóo tanná bí òdòdó,yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo sì kọrin.Ògo Lẹbanoni yóo di tìrẹati iyì Kamẹli ati ti Ṣaroni.Wọn óo rí ògo OLUWA,wọn óo rí ọlá ńlá Ọlọrun wa.

3 Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró.Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun.

4 Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé:“Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù.Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san,ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun;ó ń bọ̀ wá gbà yín là.”

5 Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà,etí adití yóo sì ṣí;

6 arọ yóo máa fò bí ìgalà,odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀.Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjùàwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.

7 Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omiilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi,ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà,èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀.

8 Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀,a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́;nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá,àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀.

9 Kò ní sí kinniun níbẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀.A kò ní rí wọn níbẹ̀,àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀.

10 Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada,wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin,ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn.Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbàìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.