Aisaya 38 BM

Àìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀

1 Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.”

2 Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA,

3 ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

4 OLUWA bá sọ fún Aisaya pé

5 kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀.

6 OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó.

21 Aisaya bá sọ fún Hesekaya pé kí wọn bá a wá èso ọ̀pọ̀tọ́ kí wọn lọ̀ ọ́, kí wọn fi lé ojú oówo tí ó mú un, kí ó lè gbádùn.

22 Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa?

7 Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí:

8 Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.

Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ

9 Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí:

10 Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi.

11 Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,ati pé n kò ní sí láàyè mọ́láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni.

12 A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi.

13 Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun.Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni.

14 Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀,mò ń ké igbe arò bí àdàbà.Mo wòkè títí ojú ń ro mí,ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi.

15 Ṣugbọn kí ni mo lè sọ?Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀,òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe éOorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́.

16 OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè,ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè.Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè.

17 Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ;ìwọ ni o dì mí mú,tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun,nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé.

18 Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́;kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú,wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́.

19 Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́bí mo ti yìn ọ́ lónìí.Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ.

20 OLUWA yóo gbà mí là,a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA,ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.