1 Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀,kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ;
2 bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú,tí iná sì ń mú kí omi hó.Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ,kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ!
3 Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù,tí ẹnikẹ́ni kò retí,o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ.
4 Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
5 Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́,àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn,o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀,a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́.Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà?
6 Gbogbo wa dàbí aláìmọ́,gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin.Gbogbo wa rọ bí ewé,àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn.
7 Kò sí ẹnìkan tí ń gbadura ní orúkọ rẹ,kò sí ẹni tí ń ta ṣàṣà láti dìmọ́ ọ;nítorí pé o ti fojú pamọ́ fún wa,o sì ti pa wá tì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8 Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa,amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò;iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa.
9 OLUWA má bínú pupọ jù,má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae.Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò,nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa.
10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀,Sioni ti di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu sì ti di ahoro.
11 Wọ́n ti dáná sun ilé mímọ́ wa tí ó lẹ́wà,níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,gbogbo ibi dáradára tí a ní, ló ti di ahoro.
12 OLUWA, ṣé o kò ní ṣe nǹkankan sí ọ̀rọ̀ yìí ni?Ṣé o óo dákẹ́, o óo máa fìyà jẹ wá ni?