Aisaya 46 BM

1 “Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò.Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà.Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù.

2 Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò,wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀.Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn.

3 “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù;ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín,tí mo sì gbé láti inú oyún.

4 Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín,n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí.Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín,n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là.

5 “Ta ni ẹ óo fi mí wé?Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi?Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà?

6 Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò,wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n.Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa.Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín.

7 Wọn á gbé e lé èjìká wọn,wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀.Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan.Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́,kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀.

8 “Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò,ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀.

9 Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́,nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́.Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi.

10 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn.Láti ìgbà àtijọ́,ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀.Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ,n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’

11 Mo pe idì láti ìlà oòrùn,mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá.Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ,mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é.

12 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà.

13 Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́,ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé.N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.”