1 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun.Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè,láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí,láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi.
2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú,ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀,ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú,ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀.
3 Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli,àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.”
4 Ṣugbọn mo dáhùn pé,“Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù.Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù,sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.”Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi.
5 Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún,kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá,ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA,Ọlọrun mi sì ti di agbára mi.
6 OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun,láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ.Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdèkí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.
7 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ,fún ẹni tí ayé ń gàn,tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra,iranṣẹ àwọn aláṣẹ,ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde,àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀.Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo,Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”
8 OLUWA ní,“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn,lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.Mo ti pa ọ́ mọ́,mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé,láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀,láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro.
9 Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà,gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn.
10 Ebi kò ní pa wọ́n,òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n,atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n,nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn,yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn.
11 “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà,n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi.
12 Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá,láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.”
13 Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀,ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin,nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.
14 Sioni ń wí pé,“OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀,Oluwa mi ti gbàgbé mi.”
15 OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú?Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀?Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé.Èmi kò ní gbàgbé rẹ.
16 Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi,àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo.
17 “Àwọn ọmọ rẹ tí ń pada bọ̀ kíákíá,àwọn olùparun rẹ yóo jáde kúrò ninu rẹ.
18 Gbójú sókè, kí o wò yíká,gbogbo àwọn ọmọ rẹ péjọ, wọ́n tọ̀ ọ́ wá.OLUWA fi ara rẹ̀ búra pé,o óo gbé wọn wọ̀ bí nǹkan ọ̀ṣọ́ ara.O óo wọ̀ wọ́n bí ìgbà tí iyawo kó ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀.
19 “Dájúdájú ilẹ̀ rẹ tí ó ti di aṣálẹ̀,ati àwọn tí ó ti di ahoro,yóo kéré fún àwọn tí yóo máa gbé inú rẹ̀ tí ó bá yá,a óo sì lé àwọn tí ó pa ọ́ run jìnnà sí ọ.
20 Àwọn ọmọ tí o bí ní àkókò ìgbèkùn rẹyóo sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ pé,‘Ibí yìí kéré jù fún wa,fún wa ní àyè sí i láti máa gbé.’
21 O óo bèèrè lọ́kàn ara rẹ nígbà náà pé,‘Ta ni ó bí àwọn ọmọ wọnyi fún mi?Ṣebí àwọn ọmọ mi ti kú, mo ti yàgàn,mo sì lọ sí ìgbèkùn lóko ẹrú.Ta ni ó wá tọ́ àwọn wọnyi dàgbà?Ṣebí èmi nìkan ni mo ṣẹ́kù,níbo ni àwọn wọnyi ti wá?’ ”
22 OLUWA Ọlọrun ní,“Wò ó, n óo gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè.N óo gbé àsíá mi sókè sí àwọn eniyan,wọn óo gbé àwọn ọmọ rẹ ọkunrin mọ́ àyà wọnwọn óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin sí èjìká.
23 Àwọn ọba ni yóo máa tọ́jú rẹ bíi baba,àwọn ayaba yóo sì máa tọ́jú rẹ bí ìyá,ní ìdojúbolẹ̀ ni wọn óo máa tẹríba fún ọ,wọn óo sì máa pọ́n eruku ẹsẹ̀ rẹ lá.O óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA,ojú kò ní ti àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé mi.”
24 Ǹjẹ́ a lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára,tabi kí á gba òǹdè lọ́wọ́ òkúrorò eniyan?
25 OLUWA ní:“Bí ó bá tilẹ̀ ṣeéṣe láti gba òǹdè lọ́wọ́ alágbára,tabi láti gba ìkógun lọ́wọ́ òkúrorò eniyan.N óo bá àwọn tí ó ń bá ọ jà jà,n óo sì gba àwọn ọmọ rẹ là.
26 N óo mú kí àwọn tó ń ni ọ́ lára máa pa ara wọn jẹ:wọn óo máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn, bí ẹni mu ọtí,gbogbo ayé yóo sì mọ̀ nígbà náà pé,èmi ni OLUWA, Olùgbàlà rẹ,Olùràpadà rẹ, Ọlọrun alágbára Jakọbu.”