Aisaya 22 BM

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu

1 Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àfonífojì ìran:Kí ni gbogbo yín ń rò tí ẹ fi gun orí òrùlé lọ,

2 ẹ̀yin tí ìlú yín kún fún ariwo, tí ẹ jẹ́ kìkì ìrúkèrúdò ati àríyá?Gbogbo àwọn tí ó kú ninu yín kò kú ikú idà,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú lójú ogun.

3 Gbogbo àwọn ìjòyè ìlú yín parapọ̀ wọ́n sálọ,láì ta ọfà ni ọ̀tá mú wọn.Gbogbo àwọn tí wọn rí ni wọ́n mú,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sá jìnnà.

4 Nítorí náà, ni mo ṣe sọ pé,“Ẹ ṣíjú kúrò lára miẹ jẹ́ kí n sọkún, kí n dami lójú pòròpòrò,ẹ má ṣòpò pé ẹ óo rẹ̀ mí lẹ́kún,nítorí ìparun àwọn ará Jerusalẹmu, àwọn eniyan mi.”

5 Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,ọjọ́ ìrúkèrúdò ati ìdágìrì ati ìdàrúdàpọ̀, ní àfonífojì ìran.Ọjọ́ wíwó odi ìlú palẹ̀ati igbe kíké láàrin àwọn òkè ńlá.

6 Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká,pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin,àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn.

7 Àwọn àfonífojì dáradára yín kún fún kẹ̀kẹ́-ogunàwọn ẹlẹ́ṣin sì dúró sí ipò wọn lẹ́nu ibodè;

8 ó ti tú aṣọ lára Juda.Ní ọjọ́ náà, ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ìjà tí ó wà ninu Ilé-Igbó,

9 ẹ rí i pé ibi tí ògiri ìlú Dafidi ti sán pọ̀, ẹ sì gbá omi inú adágún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jọ.

10 Ẹ ka iye ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu, ẹ sì wó àwọn kan palẹ̀ ninu wọn, kí ẹ lè rí òkúta tún odi ìlú ṣe.

11 Ẹ wa kòtò sí ààrin ògiri mejeeji, Kí ẹ lè rí ààyè fa omi inú odò àtijọ́ sí. Ṣugbọn ẹ kò wo ojú ẹni tí ó ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bìkítà fún ẹni tí ó ṣètò rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá.

12 Ní ọjọ́ náà,OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé,kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀,kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

13 Ṣugbọn dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀,ẹ̀ ń yọ̀, inú yín ń dùn.Ẹ̀ ń pa mààlúù, ẹ̀ ń pa aguntan,ẹ̀ ń jẹ ẹran, ẹ̀ ń mu ọtí waini.Ẹ̀ ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á jẹ, kí á mu!Nítorí pé lọ́la ni a óo kú.”

14 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé:“A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yíntítí tí ẹ óo fi kú.”

Ìkìlọ̀ fún Ṣebina

15 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Lọ bá Ṣebina, iranṣẹ ọba, tí ó jẹ́ olórí ní ààfin ọba, Kí o bi í pé:

16 ‘Kí ni o fẹ́ máa ṣe níhìn-ín? Ta ni o sì ní níhìn-ín tí o fi gbẹ́ ibojì síhìn-ín fún ara rẹ? Ìwọ tí o gbẹ́ ibojì sórí òkè, tí o kọ́ ilé fún ara rẹ ninu àpáta?

17 Wò ó! OLUWA yóo fi tipátipá wọ́ ọ sọnù ìwọ alágbára. Yóo gbá ọ mú tipátipá.

18 Yóo fì ọ́ nàkànnàkàn, yóo sì sọ ọ́ nù bíi bọ́ọ̀lù, sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, níbẹ̀ ni óo kú sí. Níbẹ̀ ni àwọn kẹ̀kẹ́-ogun rẹ tí ó dára yóo wà, ìwọ tí ò ń kó ìtìjú bá ilé OLUWA rẹ.

19 N óo tì ọ́ kúrò ní ààyè rẹ, n óo fà ọ́ lulẹ̀ kúrò ní ipò rẹ.’

20 “Ní ọjọ́ náà, n óo pe Eliakimu, iranṣẹ mi, ọmọ Hilikaya.

21 N óo gbé aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n óo sì dì í ní àmùrè rẹ; n óo gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́, yóo sì di baba fún àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn ará ilé Juda.

22 N óo fi í ṣe alákòóso ilé Dafidi. Ìlẹ̀kùn tí ó bá ṣí, kò ní sí ẹni tí yóo lè tì í; èyí tí ó bá tì, kò ní sí ẹni tí yóo lè ṣí i.

23 N óo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí èèkàn tí a kàn mọ́ ilẹ̀ tí ó le, yóo di ìtẹ́ iyì fún ilé baba rẹ̀.

24 “Gbogbo ẹbí rẹ̀ ní agboolé baba rẹ̀ yóo di ẹrú rẹ̀, ati àwọn ọmọ ati àwọn ohun èlò, láti orí ife ìmumi, títí kan ìgò ọtí.”

25 OLUWA àwọn ọmọ-ogun ní, “Ní ọjọ́ náà, èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gbọningbọnin yóo yọ, wọn yóo gé e, yóo sì wó lulẹ̀, ẹrù tí wọn fi kọ́ lórí rẹ̀ yóo sì já dànù.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA sọ.