Aisaya 31 BM

Ọlọrun Yóo Dáàbò Bo Jerusalẹmu

1 Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé!Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin;tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀,tí wọ́n gbójú lé ẹṣinnítorí pé wọ́n lágbára!Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli,wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.

2 Bẹ́ẹ̀ ni ó gbọ́n,ó sì mọ ọ̀nà tí ó fi lè mú kí àjálù dé bá eniyan,kì í sọ̀rọ̀ tán, kó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada.Ṣugbọn yóo dìde sí ìdílé àwọn aṣebi,ati àwọn tí ń ti àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn.

3 Eniyan sá ni àwọn ará Ijipti,wọn kìí ṣe Ọlọrun.Ẹranko lásán sì ni ẹṣin wọnwọn kì í ṣe àǹjọ̀nnú.Bí OLUWA bá na ọwọ́, tí ó bá gbá wọn mú,ẹni tí ń ranni lọ́wọ́ yóo fẹsẹ̀ kọ,ẹni tí à ń ràn lọ́wọ́ yóo ṣubú;gbogbo wọn yóo sì jọ ṣègbé pọ̀.

4 Nítorí OLUWA sọ fún mi pé,“Bí kinniun tabi ọmọ kinniunti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa,tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan,tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀,tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á;bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀,yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká.

5 Bí àwọn ẹyẹ tií da ìyẹ́ bo ìtẹ́ wọn,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogunyóo dáàbò bo Jerusalẹmu,yóo dáàbò bò ó, yóo sì gbà á sílẹ̀yóo dá a sí, yóo sì yọ ọ́ kúrò ninu ewu.”

6 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ẹ pada sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣàìgbọràn sí lọpọlọpọ.

7 Nítorí pé ní ọjọ́ náà, olukuluku yóo gbé àwọn ère fadakaati ère wúrà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe sọnù,àwọn ère tí ó mú wọn dẹ́ṣẹ̀.

8 Idà ni yóo pa Asiria, ṣugbọn kì í ṣe láti ọwọ́ eniyan;idà tí kò ní ọwọ́ eniyan ninu ni yóo pa á run.Yóo sá lójú ogun,a óo sì kó àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lọ máa ṣiṣẹ́ tipátipá.

9 Ẹ̀rù yóo ba ọba Asiria, yóo sálọ.Ìpayà yóo mú kí àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ju àsíá sílẹ̀.OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀,OLUWA tí iná rẹ̀ wà ní Sioni,tí ojú ààrò rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.