1 OLUWA ní:“Àwọn ọmọ aláìgbọràn gbé.Àwọn tí wọn ń dá àbá tí ó yàtọ̀ sí tèmi,tí wọn ń kó ẹgbẹ́ jọ,ṣugbọn tí kìí ṣe nípa ẹ̀mí mi;kí wọ́n lè máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.
2 Wọ́n múra, wọ́n gbọ̀nà Ijiptiláì bèèrè ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ mi.Wọ́n lọ sápamọ́ sí abẹ́ ààbò Farao,wọ́n lọ wá ààbò ní Ijipti.
3 Nítorí náà, ààbò Farao yóo di ìtìjú fún wọn,ibi ìpamọ́ abẹ́ Ijipti yóo di ìrẹ̀sílẹ̀ fún wọn.
4 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí wọn ti lọ sí Soani,tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé Hanesi.
5 Ojú yóo tì wọ́n, nítorí wọn ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́.Wọn kò lè rí ìrànwọ́ tabi anfaani kankan níbẹ̀, bíkòṣe ìtìjú ati ẹ̀gàn.”
6 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí:“Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí.Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá.Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun,ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò.Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani.
7 Nítorí ìmúlẹ̀mófo ni ìrànwọ́ Ijipti.Nítorí náà ni mo ṣe pè é ní,‘Rahabu tí ń jókòó lásán.’ ”
8 Nisinsinyii lọ kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú wọn,kí o sì kọ ọ́ sinu ìwé,kí ó lè wà títí di ẹ̀yìn ọ̀la,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí lae;
9 nítorí aláìgbọràn eniyan ni wọ́n,Òpùrọ́ ọmọ tí kìí fẹ́ gbọ́ ìtọ́ni OLUWA.
10 Wọ́n á máa sọ fún àwọn aríran pé,“Ẹ má ríran mọ.”Wọ́n á sì máa sọ fún àwọn wolii pé,“Ẹ má sọ àsọtẹ́lẹ̀ òtítọ́ fún wa mọ́,ọ̀rọ̀ dídùn ni kí ẹ máa sọ fún wa,kí ẹ sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn fún wa.
11 Ẹ fi ojú ọ̀nà sílẹ̀, ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà,ẹ má sọ nípa Ẹni Mímọ́ Israẹli fún wa mọ́.”
12 Nítorí náà, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Nítorí pé ẹ kẹ́gàn ọ̀rọ̀ yìí,ẹ gbẹ́kẹ̀lé ìninilára ati ẹ̀tàn,ẹ sì gbára lé wọn,
13 nítorí náà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dá yìí;yóo dàbí ògiri gíga tí ó là, tí ó sì fẹ́ wó;lójijì ni yóo wó lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.
14 Wíwó rẹ̀ yóo dàbí ìgbà tí eniyan la ìkòkò mọ́lẹ̀,tí ó fọ́ yángá-yángá,tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò rí àpáàdì kan mú jáde ninu rẹ̀,tí a lè fi fọn iná ninu ààrò,tabi èkúfọ́, tí a lè fi bu omi ninu odò.”
15 Nítorí OLUWA Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli ní:“Bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì farabalẹ̀,ẹ óo rí ìgbàlà;bí ẹ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,ẹ óo lágbára.Ṣugbọn ẹ kọ̀.
16 Ẹ sọ pé ó tì o, ẹ̀yin óo gun ẹṣin sálọ ni.Nítorí náà sísá ni ẹ óo sálọ.Ẹ sọ pé ẹṣin tí ó lè sáré ni ẹ óo gùn.Nítorí náà àwọn tí yóo máa le yín,wọn óo lè sáré gan-an ni.
17 Ẹgbẹrun ninu yín yóo sá fún ẹyọ ọ̀tá yín kan,gbogbo yín yóo sì sá fún ẹyọ eniyan marun-untítí tí àwọn tí yóo kú ninu yín yóo fi dàbí igi àsíá lórí òkè.Wọn óo dàbí àsíá ati àmì lórí òkè.”
18 Nítorí náà OLUWA ń dúró dè yín,ó ti ṣetán láti ṣàánú yín.Yóo dìde, yóo sì ràn yín lọ́wọ́.Nítorí Ọlọrun Olódodo ni OLUWA.
19 Ẹ̀yin ará Sioni tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ kò ní sọkún mọ́. OLUWA yóo ṣàánú yín nígbà tí ẹ bá ké pè é, yóo sì da yín lóhùn nígbà tí ó bá gbọ́ igbe yín.
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ ní ọpọlọpọ ìṣòro, yóo sì jẹ́ kí ẹ ṣe ọpọlọpọ wahala, sibẹsibẹ olùkọ́ yín kò ní farapamọ́ fun yín mọ́, ṣugbọn ẹ óo máa fi ojú yín rí i.
21 Bí ẹ bá fẹ́ yapa sí apá ọ̀tún tabi apá òsì, ẹ óo máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn yín tí yóo máa wí pé, “Ọ̀nà nìyí, ibí ni kí ẹ gbà.”
22 Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”
23 OLUWA yóo sì fi òjò ibukun sí orí èso tí ẹ gbìn sinu oko, nǹkan ọ̀gbìn yín yóo sì so lọpọlọpọ. Ní àkókò náà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí yóo máa jẹ ní pápá oko yóo pọ̀.
24 Àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ fí ń ṣe iṣẹ́ lóko yóo máa jẹ oko tí a fi iyọ̀ sí; tí a ti gbọn ìdọ̀tí kúrò lára rẹ̀.
25 Omi yóo máa ṣàn jáde láti orí gbogbo òkè gíga ati gbogbo òkè ńlá, ní ọjọ́ tí ọpọlọpọ yóo kú, nígbà tí ilé ìṣọ́ bá wó lulẹ̀.
26 Òṣùpá yóo mọ́lẹ̀ bí oòrùn; oòrùn yóo mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po meje, ní ọjọ́ tí OLUWA yóo bá di ọgbẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí yóo sì wo ọgbẹ́ tí ó dá sí wọn lára sàn.
27 Ẹ wo OLUWA tí ń bọ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè,ó ń bọ̀ tìbínú-tìbínú;ninu èéfín ńlá tí ń lọ sókè.Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kún fún ibinu;ahọ́n rẹ̀ dàbí iná tí ń jóni run.
28 Èémí rẹ̀ dàbí odò tí ó ṣàn kọjá bèbè rẹ̀tí ó lè mu eniyan dé ọrùn.Yóo fi ajọ̀ ìparun jọ àwọn orílẹ̀-èdè,yóo sì fi ìjánu tí ń múni ṣìnà bọ àwọn eniyan lẹ́nu.
29 Ẹ óo kọ orin kan bí orin alẹ́ ọjọ́ àjọ̀dún mímọ́,inú yín yóo sì dùn bíi ti ẹni tí ń jó ijó fèrè lọsórí òkè OLUWA, àpáta Israẹli.
30 OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó lógo,yóo sì jẹ́ kí ẹ rí ọwọ́ rẹ̀ tí yóo fà yọ pẹlu ibinu ńláati ninu iná ajónirun;pẹlu ẹ̀fúùfù ati ìjì líle ati òjò yìnyín.
31 Ìbẹ̀rù-bojo yóo mú àwọn ará Asirianígbà tí wọ́n bá gbóhùn OLUWA,nígbà tí ó bá fi kùmọ̀ rẹ̀ lù wọ́n.
32 Ìró ọ̀pá tí OLUWA yóo fi nà wọ́n yóo dàbí ìró aro ati dùùrù.OLUWA yóo dojú ogun kọ wọ́n.
33 Nítorí pé a ti pèsè iná ìléru sílẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ fún ọba Asiria;iná ńlá tí ń jó pẹlu ọpọlọpọ igi.Èémí OLUWA tó dàbí ìṣàn imí-ọjọ́ ni yóo ṣá iná sí i.