Aisaya 55 BM

Àánú Ọlọrun

1 OLUWA ní,“Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà;bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́,ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ.Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́,kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé.

2 Kí ló dé tí ẹ̀ ń ná owó yín lórí ohun tí kì í ṣe oúnjẹ?Tí ẹ sì ń ṣe làálàá lórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn?Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára,kí ẹ sì jẹ ohun tí ó dára,ẹ jẹ oúnjẹ aládùn, kí inú yín ó dùn.

3 “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi,ẹ gbọ́ ohun tí mò ń wí kí ẹ lè yè.N óo ba yín dá majẹmu ayérayé,ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún Dafidi.

4 Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan,olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè.

5 O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí,àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ,ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.”

6 Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i,ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

7 Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀,kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀,kí ó yipada sí OLUWA,kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀.Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa,nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ.

8 OLUWA ní,“Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín,

9 Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,tí èrò mi sì ga ju èrò yín.

10 “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run,tí wọn kì í pada sibẹ mọ́,ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀,tí ń mú kí nǹkan hù jáde;kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn,kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ.

11 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí,kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe,yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí.

12 “Nítorí tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa jáde ní Babiloni,alaafia ni wọ́n óo fi máa sìn yín sọ́nà,òkè ńlá ati kéékèèké yóo máa kọrin níwájú yín.Gbogbo igi inú igbó yóo sì máa pàtẹ́wọ́,

13 igi Sipirẹsi ni yóo máa hù dípò igi ẹlẹ́gùn-ún,igi Mitili ni yóo sì máa hù dípò ẹ̀gún ọ̀gàn,yóo jẹ́ àmì ìrántí fún OLUWA,ati àpẹẹrẹ ayérayé tí a kò ní parẹ́.”