Aisaya 26 BM

Orin Ìgbàlà

1 Ní àkókò náà,orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé:“A ní ìlú tí ó lágbára,ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò.

2 Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè,kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé.

3 O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé,nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4 Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae,nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun.

5 Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀,ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀,ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata,ó fà á sọ sinu eruku.

6 Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.”

7 Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodoó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán.

8 Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA,orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́.

9 Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́,mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọnítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyéni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo.

10 Bí a bá ṣàánú ẹni ibi,kò ní kọ́ láti ṣe rere.Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo,kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA.

11 OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà,ṣugbọn wọn kò rí i.Jẹ́ kí wọn rí i péọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún,kí ojú sì tì wọ́n.Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.

12 OLUWA ìwọ yóo fún wa ní alaafia,nítorí pé ìwọ ni o ṣe gbogbo iṣẹ́ wa fún wa.

13 OLUWA, Ọlọrun wa,àwọn oluwa mìíràn ti jọba lórí waṣugbọn orúkọ rẹ nìkan ni àwa mọ̀.

14 Wọ́n ti kú, wọn kò ní wà láàyè mọ́,ẹ̀mí wọn kò ní dìde mọ́ ní isà òkú.Nítorí bẹ́ẹ̀ ni o ṣe jẹ wọ́n níyà,o sì pa wọ́n run,o sì ti sọ gbogbo ìrántí wọn di ohun ìgbàgbé.

15 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i,OLUWA, o ti bukun orílẹ̀-èdè náà,gbogbo ààlà ilẹ̀ náà ni o ti bì sẹ́yìn,o sì ti buyì kún ara rẹ.

16 OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ,wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà.

17 Bí aboyún tí ó fẹ́ bímọ,tí ó ń yí, tí ó sì ń ké ìrora,nígbà tí àkókò àtibímọ rẹ̀ súnmọ́ tòsíbẹ́ẹ̀ ni a rí nítorí rẹ, OLUWA.

18 A wà ninu oyún, ara ń ro wá,a ní kí a bí, òfo ló jáde.A kò ṣẹgun ohunkohun láyébẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń gbé ayé kò tíì ṣubú.

19 Àwọn òkú wa yóo jí,wọn óo dìde kúrò ninu ibojì.Ẹ tají kí ẹ máa kọrin,ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀.Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín,ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.

Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò

20 Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,ẹ wọ inú yàrá yín,kí ẹ sì ti ìlẹ̀kùn mọ́rí;ẹ farapamọ́ fún ìgbà díẹ̀,títí tí ibinu OLUWA yóo fi kọjá.

21 OLUWA óo yọ láti ibùgbé rẹ̀,láti fi ìyà jẹ àwọn tí ń gbé inú ayé, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,ilẹ̀ yóo tú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sórí rẹ̀ jáde,kò sì ní bo àwọn tí a pa mọ́lẹ̀ mọ́.