1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí:OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti.Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀,ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú.
2 N óo dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Ijipti,olukuluku yóo máa bá arakunrin rẹ̀ jà,àwọn aládùúgbò yóo máa bá ara wọn jà,ìlú kan yóo gbógun ti ìlú keji,ìjọba yóo máa dìde sí ara wọn.
3 Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti,n óo sọ ète wọn di òfo.Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó.
4 Ṣugbọn n óo fi Ijipti lé aláìláàánú akóniṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́ìkà kan ni yóo sì jọba lé wọn lórí,bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.
5 Omi odò Naili yóo gbẹ,yóo gbẹ, àgbẹkanlẹ̀.
6 Gbogbo odò wọn yóo máa rùn,gbogbo àwọn odò tí ó ṣàn wọ odò Naili ní Ijipti,ni yóo fà, tí yóo sì gbẹ:Gbogbo koríko odò yóo rà.
7 Etí odò Naili yóo di aṣálẹ̀,gbogbo ohun tí wọ́n bá gbìn sibẹ yóo gbẹ,ẹ̀fúùfù óo sì gbá wọn dànù.
8 Àwọn apẹja tí ń fi ìwọ̀ ninu odò Nailiyóo ṣọ̀fọ̀,wọn óo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn;àwọn tí ń fi àwọ̀n pẹja yóo kérora.
9 Ìdààmú yóo bá àwọn tí ó ń hun aṣọ funfun,ati àwọn ahunṣọ tí ń lo òwú funfun.
10 Àwọn eniyan pataki ilẹ̀ náà yóo di ẹni ilẹ̀,ìbànújẹ́ yóo sì bá àwọn alágbàṣe.
11 Òmùgọ̀ ni àwọn olórí wọn ní Soani;ìmọ̀ràn wèrè sì ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìgbìmọ̀ Farao ń fún eniyan.Báwo ni eniyan ṣe lè sọ fún Farao pé,“Ọmọ Ọlọ́gbọ́n eniyan ni mí,ọmọ àwọn ọba àtijọ́.”
12 Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rẹ dà?Níbo ni wọ́n wà kí wọ́n sọ fún ọ,kí wọ́n sì fi ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti ṣe sí Ijipti hàn ọ́.
13 Àwọn olórí wọn ní Soani ti di òmùgọ̀,àwọn olórí wọn ní Memfisi sì ti gba ẹ̀tàn;àwọn tí wọ́n jẹ́ òpómúléró ní ilẹ̀ Ijipti ti ṣi Ijipti lọ́nà.
14 OLUWA ti dá èdè-àìyedè sílẹ̀ láàrin wọn,wọ́n sì ti ṣi Ijipti lọ́nà ninu gbogbo ìṣe rẹ̀,bí ìgbà tí ọ̀mùtí bá ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n ninu èébì rẹ̀.
15 Kò sí nǹkankan tí ẹnìkan lè ṣe fún Ijipti,kì báà jẹ́ ọlọ́lá tabi mẹ̀kúnnù,kì báà jẹ́ eniyan pataki tabi ẹni tí kò jẹ́ nǹkan.
16 Tí ó bá di ìgbà náà, àwọn ará Ijipti yóo di obinrin. Wọn yóo máa gbọ̀n, fún ẹ̀rù, nígbà tí OLUWA àwọn ọmọ ogun bá gbá wọn mú.
17 Ilẹ̀ Juda yóo di ẹ̀rù fún àwọn ará Ijipti, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóo bẹ̀rù nítorí ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu láti ṣe sí Ijipti.
18 Tó bá di ìgbà náà, ìlú marun-un yóo wà ní ilẹ̀ Ijipti, tí wọn yóo máa sọ èdè Kenaani; wọ́n óo búra láti jẹ́ ti OLUWA àwọn ọmọ ogun.Orúkọ ọ̀kan ninu wọn yóo máa jẹ́ ìlú Oòrùn.
19 Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA láàrin ilẹ̀ Ijipti, ọ̀wọ̀n OLUWA kan yóo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ààlà ilẹ̀ rẹ̀.
20 Yóo jẹ́ àmì ati ẹ̀rí fún OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe OLUWA nítorí àwọn aninilára, OLUWA yóo rán olùgbàlà tí yóo gbà wọ́n sí wọn.
21 OLUWA yóo sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Ijipti, wọn óo sì mọ OLUWA nígbà náà. Wọ́n yóo máa sin OLUWA pẹlu ẹbọ ati ẹbọ sísun; wọn óo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, wọn yóo sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.
22 OLUWA yóo fìyà jẹ àwọn ará Ijipti ṣugbọn yóo wò wọ́n sàn, wọn yóo pada sọ́dọ̀ OLUWA, yóo gbọ́ adura wọn, yóo sì wò wọ́n sàn.
23 Tó bá di ìgbà náà, ọ̀nà tí ó tóbi kan yóo wà láti Ijipti dé Asiria–àwọn ará Asiria yóo máa lọ sí Ijipti, àwọn ará Ijipti yóo sì máa lọ sí Asiria; àwọn ará Ijipti yóo máa jọ́sìn pẹlu àwọn ará Asiria.
24 Ní àkókò náà, Israẹli yóo ṣìkẹta Ijipti ati Asiria, wọn yóo sì jẹ́ ibukun lórí ilẹ̀ fún àwọn ará Ijipti, àwọn eniyan mi.
25 Tí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti súre fún pé, “Ibukun ni fún Ijipti, àwọn eniyan mi, ati fún Asiria tí mo fi ọwọ́ mi dá, ati fún Israẹli ìní mi.”