Aisaya 56 BM

Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun

1 OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́,kí ẹ sì máa ṣe òdodo;nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́,ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi.

2 Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀,ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e,tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi,tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.”

3 Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé,“Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.”Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé,“Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”

4 Nítorí OLUWA ní,“Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

5 n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.

6 “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

7 n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”

8 OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”

A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli lẹ́bi

9 Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀,gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun.

10 Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹligbogbo wọn kò mọ nǹkankan.Ajá tí ó yadi ni wọ́n,wọn kò lè gbó;oorun ni wọ́n fẹ́ràn.Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.

11 Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì,wọn kì í yó.Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan.Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn,olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.

12 Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini,ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó,bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.”