1 Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ.
2 Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀,òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ,ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ.
3 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ,àwọn ọba yóo sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ rẹ tí ń tàn.
4 Gbé ojú sókè kí o wò yíká,gbogbo wọn kó ara wọn jọ, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ ọkunrin yóo wá láti òkèèrè,a óo sì gbé àwọn ọmọ rẹ obinrin lé apá wá.
5 Nígbà tí o bá rí wọn,inú rẹ yóo dùn,ara rẹ óo yá gágá.Ọkàn rẹ yóo kún fún ayọ̀,nítorí pé a óo gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ inú òkun wá sọ́dọ̀ rẹ.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo kó ọrọ̀ wọn wá fún ọ.
6 Ogunlọ́gọ̀ ràkúnmí yóo yí ọ ká,àwọn ọmọ ràkúnmí Midiani ati Efa.Gbogbo àwọn tí wọn wà ní Ṣeba yóo wá,wọn óo mú wúrà ati turari wá;wọn óo sì máa pòkìkí OLUWA.
7 Gbogbo ẹran ọ̀sìn Kedari ni wọ́n óo kó wá fún ọ,wọn óo kó àgbò Nebaiotu wá ta ọ́ lọ́rẹ.Wọn óo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi,ilé mi lógo, ṣugbọn n óo tún ṣe é lógo sí i.
8 Ta ni àwọn wọnyi tí ń fò lọ bí ìkùukùu?Bí ìgbà tí àwọn àdàbà bá ń fò lọ sí ibi ìtẹ́ wọn?
9 Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí,ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwajuwọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè,wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn;nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ,ati Ẹni Mímọ́ Israẹli,nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo.
10 OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ,àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ;nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́.Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ.
11 Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo,a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru;kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ,pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju.
12 Orílẹ̀-èdè tabi ilẹ̀ ọba tí kò bá sìn ọ́ yóo parun,wọn óo di àwópalẹ̀ patapata.
13 “Ògo Lẹbanoni yóo wá sí ọ̀dọ̀ rẹ:igi sipirẹsi, igi firi, ati igi pine;láti bukun ẹwà ilé mímọ́ mi,n óo sì ṣe ibi ìtìsẹ̀ mi lógo.
14 Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá,wọn óo tẹríba fún ọ;gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ,yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ;wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.
15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́,wọ́n sì kórìíra rẹ,tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́,n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae;àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran.
16 O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,o óo mu wàrà àwọn ọba.O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ,ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu.
17 “Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá.Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá.Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá.Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá.N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia,àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo.
18 Kò tún ní sí ìró ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ rẹ mọ́,kò sì ní sí ìdágìrì ati ìparun ní ibodè rẹ,o óo máa pe odi rẹ ní ìgbàlà,o óo sì máa pe ẹnubodè rẹ ní ìyìn.
19 “Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru:OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ.
20 Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn.Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin.
21 Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo,àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae.Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi,kí á baà lè yìn mí lógo.
22 Ìdílé tí ó rẹ̀yìn jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè,èyí tí ó sì kéré jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá,Èmi ni OLUWA,kíákíá ni n óo ṣe é nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó.”