Aisaya 11 BM

Ìjọba Tí Ó Tòrò

1 Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese,ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀.

2 Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e,ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye,ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára,ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA.

3 Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀kì í ṣe ohun tí ó fojú rí,tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́.

4 Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka,yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀,yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán,yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi.

5 Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀,yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀.

6 Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé,àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́,ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀,ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ.

7 Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀,àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀,kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù.

8 Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀,ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmúyóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò.

9 Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́,tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi.Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayébí omi ṣe kún gbogbo inú òkun.

Àwọn Ìgbèkùn Yóo Pada

10 Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.

11 Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun.

12 Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ.Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ,láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé.

13 Owú jíjẹ Efuraimu yóo kúrò,a óo sì pa àwọn tí ń ni Juda lára run.Efuraimu kò gbọdọ̀ jowú Juda mọ́,bẹ́ẹ̀ ni Juda kò gbọdọ̀ ni Efuraimu lára mọ.

14 Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn,wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn.Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu.Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.

15 OLUWA yóo pa Ijipti run patapata.Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati,yóo sì pín in sí ọ̀nà meje,kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá.

16 Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀;bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli,nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.