1 Wò ó! Agbára OLUWA kò dínkù, tí ó fi lè gbani là,etí rẹ̀ kò di, tí kò fi ní gbọ́.
2 Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin ati Ọlọrun yín,àìdára yín ni ó mú kí ó fojú pamọ́ fun yín,tí kò fi gbọ́ ẹ̀bẹ̀ yín.
3 Ìpànìyàn ti sọ ọwọ́ yín di aláìmọ́,ọwọ́ yín kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ ń purọ́,ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú.
4 Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre,kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo.Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé.Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín,iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.
5 Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀,ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn,ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú.Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i.
6 Òwú aláǹtakùn yín kò lè di aṣọ,eniyan kò ní fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bora.Iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni iṣẹ́ yín,ìwà ipá sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.
7 Ẹsẹ̀ yín yá sí ọ̀nà ibi,ẹ sì yára sí àtipa aláìṣẹ̀.Èrò ẹ̀ṣẹ̀ ni èrò ọkàn yín.Ọ̀nà yín kún fún ìsọdahoro ati ìparun.
8 Ẹ kò mọ ọ̀nà alaafia,kò sí ìdájọ́ òdodo ní ọ̀nà yín.Ẹ ti mú kí ọ̀nà yín wọ́,ẹni tó bá ba yín rìn kò ní ní alaafia.
9 Àwọn eniyan bá dáhùn pé,“Nítorí náà ni ìdájọ́ òtítọ́ fi jìnnà sí wa,tí òdodo kò sì fi dé ọ̀dọ̀ wà.Ìmọ́lẹ̀ ni à ń retí, ṣugbọn òkùnkùn ló ṣú,ìtànṣán oòrùn ni à ń retí, ṣugbọn ìkùukùu ni ó bolẹ̀.
10 À ń táràrà lára ògiri bí afọ́jú,à ń táràrà bí ẹni tí kò lójú.À ń kọsẹ̀ lọ́sàn-án gangan,bí ẹni tí ó jáde ní àfẹ̀mọ́júmọ́a dàbí òkú láàrin àwọn alágbára.
11 Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari,a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà.À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí;à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa.
12 “Nítorí àìdára wa pọ̀ níwájú rẹ,ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí lòdì sí wa;nítorí àwọn àìdára wa wà pẹlu wa,a sì mọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa:
13 A ń kọjá ààyè wa, à ń sẹ́ OLUWA,a sì ń yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun wa.Ọ̀rọ̀ ìninilára ati ọ̀tẹ̀ ni à ń sọ,èrò ẹ̀tàn ní ń bẹ lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ èké sì ní ń jáde lẹ́nu wa.
14 A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn,òdodo sì takété.Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́,ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé.
15 Òtítọ́ di ohun àwátì,ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.”OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo,ó sì bà á lọ́kàn jẹ́,
16 Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà,ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan.Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀,òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró.
17 Ó gbé òdodo wọ̀ bí ìgbàyà,ó fi àṣíborí ìgbàlà borí.Ó gbé ẹ̀san wọ̀ bí ẹ̀wù,ó fi bora bí aṣọ.
18 Yóo san ẹ̀san fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn,yóo bínú sí àwọn tí wọ́n lòdì sí i,yóo sì san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,ati àwọn tí ń gbé erékùṣù.
19 Wọn óo bẹ̀rù orúkọ OLUWA láti ìwọ̀ oòrùn,wọn óo bẹ̀rù ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn;nítorí yóo wá bí ìkún omi, tí ẹ̀fúùfù láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń taari.
20 OLUWA ní, “N óo wá sí Sioni bí Olùràpadà,n óo wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Jakọbu,tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.
21 “Majẹmu tí Èmi bá wọn dá nìyí: Ẹ̀mí mi tí mo fi le yín lórí, ati ọ̀rọ̀ mi tí mo fi si yín lẹ́nu, kò gbọdọ̀ kúrò lẹ́nu yín, ati lẹ́nu àwọn ọmọ rẹ, ati lẹ́nu arọmọdọmọ yín, láti àkókò yìí lọ ati títí laelae. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”