Aisaya 33 BM

Adura fún Ìrànlọ́wọ́

1 O gbé! Ìwọ tí ń panirun,tí ẹnìkan kò parun,ìwọ tí ò ń hùwà ọ̀dàlẹ̀nígbà tí ẹnìkan kò dà ọ́.Ìgbà tí o bá dáwọ́ ìpanirun dúró,nígbà náà ni a óo pa ìwọ gan-an run;nígbà tí o bá fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ sílẹ̀,nígbà náà ni a óo dà ọ́.

2 Ṣàánú wa OLUWA,ìwọ ni a dúró tí à ń wò.Máa ràn wá lọ́wọ́ lojoojumọ,sì máa jẹ́ olùgbàlà wa nígbà ìṣòro.

3 Àwọn orílẹ̀-èdè sá nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo tí ó dàbí ti ààrá,wọ́n fọ́n ká nígbà tí o gbéra nílẹ̀.

4 A kó ìkógun jọ bí ìgbà tí tata bo oko,àwọn eniyan dà bo ìṣúra, bí ìgbà tí eṣú bo oko.

5 A gbé OLUWA ga!Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé;yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni.

6 Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀.Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀,ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀.

7 Ẹ wò ó, àwọn alágbára ń kígbe lóde,àwọn òjíṣẹ́ alaafia ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

8 Òpópó ọ̀nà ṣófo,àwọn èrò kò rìn mọ́;wọ́n ń ba majẹmu jẹ́,wọn kò bìkítà fún ẹlẹ́rìí mọ́;wọ́n kò sì ka eniyan sí.

9 Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé.

OLUWA Kìlọ̀ fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀

10 OLUWA ní:“Ó yá tí n óo dìde,ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀.Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga.

11 Èrò yín dàbí fùlùfúlù, gbogbo ìṣe yín dàbí pòpórò ọkà.Èémí mi yóo jó yín run bí iná.

12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dàbí ìgbà tí a sun wọ́n,tí wọ́n di eérú,àní bí igi ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀, tí a sì dáná sun.

13 Ẹ̀yin tí ẹ wà lókè réré,ẹ gbọ́ ohun tí mo ṣe;ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí,ẹ kíyèsí agbára mi.”

14 Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni;ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun.Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun?Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú?

15 Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́,ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù,tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan,tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi.

16 Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀.Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé,yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.

Ọjọ́ Ọ̀la tó Lógo

17 Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀;ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu.

18 Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé:“Níbo ni akọ̀wé wà?Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà?Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?”

19 Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́,àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín,tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́.

20 Ẹ wo Sioni, ìlú tí a yà sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún.Ẹ óo fi ojú rí Jerusalẹmu, ibùgbé alaafia, tí àgọ́ rẹ̀ kò ní ṣídìí,tí èèkàn tí a fi kàn án mọ́lẹ̀ kò ní hú laelae,bẹ́ẹ̀ ni okùn tí a fi so ó mọ́lẹ̀ kò ní já.

21 Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀,yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa;níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé,ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀.

22 Nítorí pé OLUWA ni onídàájọ́ wa,òun ni alákòóso wa;OLUWA ni ọba wa,òun ni yóo gbà wá là.

23 Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú,kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́;kò sì lè gbé ìgbòkun dúró.A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà,kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀.

24 Kò sí ará ìlú kan tí yóo sọ pé,“Ara mi kò yá.”A óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.