Aisaya 2 BM

Alaafia Ayérayé

1 Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí:

2 Ní ọjọ́ iwájúòkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ,a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ.Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ.

3 Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé:“Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ,kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀,kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wáọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.”

4 Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí.Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.

5 Ẹ̀yin ìdílé Jakọbuẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA.

A óo pa Ìgbéraga Run.

6 Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù,àní, ìdílé Jakọbu.Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn,àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini,Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì.

7 Wúrà ati fadaka kún ilẹ̀ wọn,ìṣúra wọn kò sì lópin.Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lóǹkà.

8 Ilẹ̀ wọn kún fún oriṣa,wọ́n ń bọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,wọ́n ń wólẹ̀ fún ohun tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe.

9 Bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe tẹ ara rẹ̀ lórí batí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.Oluwa, máṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.

10 Ẹ wọnú àpáta lọ,kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀.Ẹ sá fún ibinu OLUWAati ògo ọlá ńlá rẹ̀.

11 A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀,a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀;OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà.

12 Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,ati àwọn ọlọ́kàn gíga,ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga.

13 Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni,tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani;

14 ati gbogbo àwọn òkè ńláńlá,ati gbogbo òkè gíga,

15 ati gbogbo ilé-ìṣọ́ gígaati gbogbo odi tí ó lágbára,

16 ati gbogbo ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Taṣiṣi,ati gbogbo ọkọ̀ tí ó dára.

17 Àwọn ọlọ́kàn gíga yóo di ẹni ilẹ̀,a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà,

18 àwọn oriṣa yóo sì pòórá patapata.

19 Àwọn eniyan yóo sá sinu ihò àpáta,wọn yóo sì wọ inú ihò ilẹ̀ lọ,nígbà tí wọ́n bá ń sá fún ibinu OLUWA,ati ògo ọlá ńlá rẹ̀nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

20 Ní ọjọ́ náà,àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù,ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ.Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán.

21 Wọn óo wọ inú pàlàpálá àpáta,ati inú ihò àwọn òkè gíga;nígbà tí wọn bá ń sá fún ibinu OLUWA,ati ògo ọlá ńlá rẹ̀,nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

22 Ẹ má gbẹ́kẹ̀lé eniyan mọ́.Ẹlẹ́mìí ni òun alára,nítorí pé kí ni ó lè ṣe?