Aisaya 57 BM

OLUWA Dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli lẹ́bi

1 Olódodo ń ṣègbé,kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i.A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé,pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.

2 Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia,wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn.

3 Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi,ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́,ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga.

4 Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sítí ẹ yọ ṣùtì sí?Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yínirú ọmọ ẹ̀tàn;

5 ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku,ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì,ati ní abẹ́ àpáta?

6 Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì,àwọn ni ẹ̀ ń sìn,àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí,àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí.Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?

7 Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ síníbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.

8 O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn.O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀.O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀,ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.

9 O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki,o kó ọpọlọpọ turari lọ,o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.

10 Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà,sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.”Ò ń wá agbára kún agbára,nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.

11 Ta ni ń já ọ láyà,tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́;tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi?Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́,ni o kò fi bẹ̀rù mi?

12 N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

13 Nígbà tí o bá kígbe,kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́.Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọAfẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ.Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí,ni yóo ni ilẹ̀ náà,òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.

Ọlọrun Ṣe Ìlérí Ìrànlọ́wọ́ ati Ìwòsàn

14 OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe,ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”

15 Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.Láti sọ ọkàn wọn jí.

16 Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,Èmi ni mo dá èémí ìyè.

17 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi,mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi;sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.

18 Mo ti rí bí ó ti ń ṣe,ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn;n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu,n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.

19 Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè,ati àwọn tí ó wà nítòsí;n óo sì wò wọ́n sàn.

20 Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun,nítorí òkun kò lè sinmi,omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.

21 Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.”Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.