Aisaya 61 BM

Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè

1 Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi,nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí,láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára.Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu,kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.

2 Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA,ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa;kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu.

3 Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni,ní inú dídùn dípò ìkáàánú,kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́,kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo,tí OLUWA gbìn,kí á lè máa yìn ín lógo.

4 Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.

5 Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;

6 ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.

7 Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji,dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín.Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín,ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.

8 OLUWA ní,“Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́,mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́.Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn,n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.

9 Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè,a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan,gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn,yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”

10 N óo máa yọ̀ ninu OLUWA,ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi.Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù,ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ;bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.

11 Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde,tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jádeníwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.