1 Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ.Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀,ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
2 Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn,sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù.Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn,kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára.
3 Nítorí o óo tàn kálẹ̀, sí apá ọ̀tún ati apá òsì,àwọn ọmọ rẹ yóo gba ìtẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè,wọn óo sì máa gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro.
4 Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́,má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́,nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ,o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́.
5 Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ,OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ,Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.
6 Nítorí OLUWA ti pè ọ́,bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́,àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀;OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
7 Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú.
8 Mo fojú mi pamọ́ fún ọ,fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ,ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ.Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9 Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi:mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii,pé n kò ní bínú sí ọ mọ́,pé n kò ní bá ọ wí mọ́.
10 Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò,tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí,ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ,majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀.Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
11 OLUWA ní:“Jerusalẹmu, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí hílàhílo bá,tí a kò sì tù ninu,òkúta tí a fi oríṣìíríṣìí ọ̀dà kùn ni n óo fi kọ́ ọ,òkúta safire ni n óo sì fi ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.
12 Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ,òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ,àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ.
13 “Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí.
14 A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo,o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́.O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ.
15 Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an,ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.”
16 OLUWA ní,“Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ,tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná,tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀,èmi náà ni mo dá apanirun,pé kí ó máa panirun.
17 Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jàtí yóo lágbára lórí rẹ.Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́,ni o óo jàre wọn.Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA,ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”