1 OLUWA ní,“Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró,àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí.Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e,yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè.
2 Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo,kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba.
3 Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú,yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́.
4 Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì,títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé.Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.”
5 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ;ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ,tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀;ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀;tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.
6 Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo,mo ti di ọwọ́ rẹ mú,mo sì pa ọ́ mọ́.Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé,mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;
7 kí o lè la ojú àwọn afọ́jú,kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́,kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
8 “Èmi ni OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ mi;n kò ní fi ògo mi fún ẹlòmíràn,n kò sì ní fi ìyìn mi fún ère.
9 Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá,àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii.Kí wọn tó yọjú jáde rárá,ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.”
10 Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA;ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé.Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun,ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun;ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn.
11 Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè,ati àwọn abúlé agbègbè Kedari;kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀,kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè.
12 Kí wọn fi ògo fún OLUWA,kí wọn kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù.
13 OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin,ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun,ó kígbe, ó sì bú ramúramù.Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀.OLUWA ní:
14 “Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́,mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo mára dúró.Ṣugbọn nisinsinyii, n óo kígbe,bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.N óo máa mí túpetúpe,n óo máa mí hẹlẹhẹlẹ.
15 N óo sọ àwọn òkè gíga ati àwọn kéékèèké di ilẹ̀,n óo mú kí gbogbo ewéko orí wọn gbẹ;n óo sọ àwọn odò di erékùṣù,n óo sì mú kí àwọn adágún omi gbẹ.
16 “N óo darí àwọn afọ́jú,n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí,n óo tọ́ wọn sọ́nà,ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí.N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn,n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú.N óo ṣe àwọn nǹkan,n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
17 A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò,ojú yóo sì tì wọ́n patapataàwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé:‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ”OLUWA ní:
18 “Gbọ́, ìwọ adití,sì wò ó, ìwọ afọ́jú, kí o lè ríran.
19 Ta ni afọ́jú, bíkòṣe iranṣẹ mi?Ta sì ni adití, bíkòṣe ẹni tí mo rán níṣẹ́?Ta ni ó fọ́jú tó ẹni tí mo yà sọ́tọ̀,tabi ta ni ojú rẹ̀ fọ́ tó ti iranṣẹ OLUWA?
20 Ó ń wo ọpọlọpọ nǹkan, ṣugbọn kò ṣe akiyesi wọn.Etí rẹ̀ là sílẹ̀,ṣugbọn kò gbọ́ràn.”
21 Ó wu OLUWA láti gbé òfin rẹ̀ gaati láti ṣe é lógo nítorí òdodo rẹ̀.
22 Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè,a sì ti kó wọn lẹ́rù,a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀,a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀,a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé:“Ẹ dá wọn pada.”
23 Èwo ninu yín ló fetí sí èyí,tabi tí yóo farabalẹ̀ gbọ́ nítorí ẹ̀yìn ọ̀la?
24 Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́,ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́?Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni,ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀;tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́.
25 Nítorí náà ó jẹ́ kí wọ́n rí ibinu òun,ó sì fi agbára ogun rẹ̀ hàn wọ́n.Ó tanná ràn án lọ́tùn-ún lósì, sibẹ kò yé e;iná jó o, sibẹsibẹ kò fi ṣe àríkọ́gbọ́n.