Aisaya 21 BM

Ìran nípa Ìṣubú Babiloni

1 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí:àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀,láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù,ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀.

2 Ìran tí a fi hàn mí yìí le:Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun,abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́.Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ!Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun!Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan.

3 Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí,gbogbo ara ní ń ro míbí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́.A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan,wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran.

4 Ọkàn mi dààmú, jìnnìjìnnì dà bò mí;wọ́n ti sọ àfẹ̀mọ́júmọ́ tí mò ń retí di ìbẹ̀rù mọ́ mi lọ́wọ́.

5 Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu.Ariwo bá ta pé“Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun!Ẹ fepo pa asà yín.”

6 Nítorí OLUWA wí fún mi pé:“Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà,kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí.

7 Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣintí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí ití àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,tí àwọn kan gun ràkúnmí,kí ó fara balẹ̀ dáradára,kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.”

8 Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé:“OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ,níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru.

9 Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀,wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!”“Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó!Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀,ó ti wó lulẹ̀ patapata.”

10 Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀,bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà,ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun,Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí.

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu

11 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu nìyí:Ẹnìkan ń pè mí láti SeiriÓ ní: “Aṣọ́nà, Òru ti rí o?Aṣọ́nà, àní òru ti rí?”

12 Aṣọ́nà bá dáhùn, ó ní:“Ilẹ̀ ń ṣú, ilẹ̀ sì ń mọ́.Bí ẹ bá tún fẹ́ bèèrè,ẹ pada wá, kí ẹ tún wá bèèrè.”

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia

13 Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia nìyí:Ninu igbó Arabia ni ẹ óo sùn, ẹ̀yin èrò ará Didani.

14 Ẹ bu omi wá fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ.Ẹ gbé oúnjẹ pàdé ẹni tí ń sá fógun, ẹ̀yin ará ilẹ̀ Tema.

15 Wọ́n ń sá fún idà,wọ́n sá fún idà lójú ogun.Wọ́n ń sá fún àwọn tafàtafà,wọ́n sá fún líle ogun.

16 OLUWA sọ fún mi pé, “Kí ó tó tó ọdún kan, ní ìwọ̀n ọdún alágbàṣe kan, gbogbo ògo Kedari yóo dópin;

17 díẹ̀ ni yóo sì kù ninu àwọn tafàtafà alágbára ọmọ Kedari; nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ló sọ bẹ́ẹ̀.”