Aisaya 66 BM

OLUWA Dá àwọn Orílẹ̀-Èdè Lẹ́jọ́

1 OLUWA ní:“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.Ilé tí ẹ kọ́ fún mi dà?Níbo sì ni ibi ìsinmi mi wà?

2 Ọwọ́ mi ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi,tèmi sì ni gbogbo wọn.Ẹni tí n óo kà kún,ni onírẹ̀lẹ̀ ati oníròbìnújẹ́ eniyan, tí ó ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ mi.

Kò Ṣeku kò Ṣẹyẹ

3 “Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ,ati ẹni tí ó pa eniyan;kò sí ìyàtọ̀.Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ,kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa.Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ,ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ,bákan náà ni wọ́n rí.Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí,kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa.Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n,wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn.

4 Èmi náà óo sì yan ìjìyà fún wọn,n óo jẹ́ kí ẹ̀rù wọn pada sórí wọn.Nítorí pé nígbà tí mo pè wọ́n, ẹnikẹ́ni wọn kò dáhùn;nígbà tí mo sọ̀rọ̀ fún wọn, wọn kò gbọ́,wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú mi,wọ́n yan ohun tí inú mi kò dùn sí.”

5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀:“Àwọn arakunrin yín tí wọn kórìíra yín,wọ́n tì yín síta nítorí orúkọ mi;wọ́n ní, ‘Jẹ́ kí OLUWA fi ògo rẹ̀ hàn,kí á lè rí ayọ̀ yín.’Ṣugbọn àwọn ni ojú yóo tì.

6 Ẹ gbọ́ ariwo ninu ìlú,ẹ gbọ́ ohùn kan láti inú Tẹmpili,ohùn OLUWA ni,ó ń san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

7 “Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ.Kí ìrora obí tó mú un,ó ti bí ọmọkunrin kan.

8 Ta ló gbọ́ irú èyí rí?Ta ló rí irú rẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan,tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan?Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí,ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin.

9 Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí,kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí?Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ,ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?”

10 Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀,ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀.

11 Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu;kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú,ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.

12 Nítorí OLUWA ní:“N óo tú ibukun sórí rẹ̀,bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn.N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè.Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú,ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀.

13 N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún,bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu.

14 Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí,bí ìgbà tí koríko bá rúwé.Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀,ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

15 Wò ó! OLUWA ń bọ̀ ninu iná,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo dàbí ìjì,láti fi ìrúnú san ẹ̀san,yóo sì fi ahọ́n iná báni wí.

16 Nítorí pé iná ni OLUWA yóo fi ṣe ìdájọ́,idà ni yóo fi ṣe ìdájọ́ fún gbogbo eniyan;àwọn tí OLUWA yóo fi idà pa yóo sì pọ̀.

17 OLUWA ní, “Àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ń lọ bọ̀rìṣà ninu àgbàlá, wọ́n ń jó ijó oriṣa, wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, ati àwọn ohun ìríra, ati èkúté! Gbogbo wọn ni yóo ṣègbé papọ̀.

18 Nítorí mo mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn ati èrò ọkàn wọn. Mò ń bọ̀ wá gbá gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà jọ. Nígbà tí wọ́n bá dé, wọ́n óo rí ògo mi.

19 “N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

20 Wọn óo sì kó gbogbo àwọn ará yín bọ̀ láti orílẹ̀-èdè gbogbo, wọn óo kó wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Wọn óo máa bọ̀ lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́-ogun, lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, wọn óo máa wá sí ìlú Jerusalẹmu, òkè mímọ́ mi, bí àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa mú ẹbọ ohun jíjẹ wọn wá sí ilé OLUWA, ninu àwo tí ó mọ́.

21 N óo mú ninu wọn, n óo fi ṣe alufaa ati ọmọ Lefi.

22 “Bí ọ̀run tuntun ati ayé tuntun tí n óo dá, yóo ṣe máa wà níwájú mi, bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ ati orúkọ rẹ̀ yóo máa wà.

23 Láti oṣù tuntun dé oṣù tuntun, ati láti ọjọ́ ìsinmi kan dé ekeji, ni gbogbo eniyan yóo máa wá jọ́sìn níwájú mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

24 Wọn óo jáde, wọn óo sì fojú rí òkú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí mi; nítorí ìdin tí ń jẹ wọ́n kò ní kú, bẹ́ẹ̀ ni iná tí ń jó wọn kò ní kú; wọn óo sì jẹ́ ohun ìríra lójú gbogbo eniyan.”